Awọn onifayawọ gboro ni Papalanto: Wọn ṣa aṣọbode ladaa, wọn tun dana sun ileeṣẹ wọn

Spread the love

Aarọ kutu ọjọ Satide ijẹrin yii ko ṣenuure fawọn oṣiṣẹ aṣọbode ilẹ wa, kọsitọọmu, ẹka tipinle Ogun rara. Diẹ lo ku ki ọkan ninu wọn,Abdullahi Muhammad Kuso, ku patapata nigba tawọn onifayawọ gbe e lẹnu iṣẹ, ti wọn ṣa a lada lai mọye ọna, ti wọn tun dana sun ileeṣẹ awọn aṣọbode naa to wa ni Ewekoro pẹlu.
Irọlẹ ọjọ Satide naa ni Alukoro ajọ kọsitọọmu nipinlẹ Ogun, Abdullai Maiwada, fi atẹjade to fi ṣalaye ohun ti oju awọn ri lọjọ naa sita. Ninu ẹ lo ti sọ pe ọna to lọ si Ilaro lati Papalanto lawọn ikọ oun wa laarọ ọjo keje, oṣu kẹje yii, ni nnkan bii aago mẹsan-an arọ ti wọn n siṣẹ wọn. Ni wọn ba ri awọn kan ti wọn n ko irẹsi ilẹ okeere tijọba ti fofin de pe ko gbọdọ wọlu gba ọna naa, wọn fee ko o apo irẹsi gọbọi wọle.
Eyi lo mu awọn aṣọbode da wọn duro, sugbọn awọn onifayawọ naa dira ogun wa gidi ni, ko si pẹ ti wọn fi sọ wahala kalẹ, ti wọn n yọ ada atawọn nnkan ija mi-in sawọn aṣọbode atawọn to n kọja lasiko naa gan-an.
Maiwada ṣalaye pe rogbodiyan nla lo ṣẹlẹ lẹsẹkẹsẹ to jẹ niṣe ni gbogbo agbegbe naa da paroparo kia, yatọ sawon onifayawọ to gba oju ọna kan ti won n bawọn eeyan oun ja gidi.
Nigba to di pe apa awọn kọsitọọmu ko ka awọn onifayawọ naa mọ ni won ranṣe si ileeṣẹ wọn to wa n’Ilaro pe ki wọn ba awọn fi awọn ọmọ ogun mi-in ti wọn le kun awọn lọwọ ranṣẹ.
N lawọn t’Ilaro ba bọ sọna lati ran wọn lọwọ, ṣugbọn awọn aṣọbode to fẹẹ lọọ gbeja naa ko tiẹ ti i debẹ ti awọn onifayawọ ti wọn ti pin ara wọn saarin ọna kiri fi ko wọn lọna, ni wọn ba tun mu awọn iyẹn naa lu bi i kiku, wọn ko si le de ọdọ awọn eeyan wọn ti wọn fẹẹ lọọ gba silẹ lọwọ iya.
Ninu ija nla naa lawọn onifayawọ ti mu kọsitọọmu kan ti wọn pe ni Abdullahi Muhammed Koso, wọn ṣa a ladaa kaakiri ara,ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun lo si wa lọsibitu ni gbogbo igba ti an ko iroyin yii jọ. Igbiyanju lo pọ ti wọn fi ri Abdullai ti wọn ṣa ladaa naa gba pada lọwọ aawọn onifayawọ, wọn fẹẹ gbe e sa lọ pata ni.
Afi bii igba ti ale iya ẹni ba ju baba ẹni lọ, to jẹ baba lo ku ta o maa pe e ni iya to jẹ awọn kọsitọọmu naa lọjọ yii ri. Nitori awọn ẹlẹru ofin to ba wọn fa a naa mura wọn wa gidi ni, iyẹn lo fi jẹ pe bi wọn ti fiya jẹ wọn tan ni wọn tun lọ si ọkan ninu ileeṣe awọn aṣọbodẹ naa to wa ni Ewekoro, nitosi ileeṣẹ simẹnti, wọn si sọna sibẹ, wọn jo o gburu gburu.
Ṣugbọn Alukoro kọsitọọmu nipinlẹ Ogun, Maiwada Abdullahi ti ni ohun to ṣẹlẹ naa ko ni i din bawọn ṣe n koju awọn onifayawọ ku, o lawọn yoo maa tẹsiwaju ni. O si kilọ fun wọn pe ki wọn jawọ ninu kiko ẹru ofin wọlu, o ni awọn yoo ri awọn to koju awọn lọjọ Satide yii mu dandan laipẹ.

(44)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.