Awọn ọmọọta da ipolongo Paṣẹda ru, wọn yinbọn lagbo Dapọ Abiọdun

Spread the love

Iwe tawọn oloṣelu kọwọ bọ lọdọ awọn ọlọpaa lọdun to kọja, pe wahala ko ni i ṣẹlẹ nibudo ipolongo ibo ko fẹrẹ nitumọ kankan rara, nitori ohun ti wọn ni ko ni i ṣẹlẹ ti n waye bayii.  Wọn ti n fibọn da ipolongo ibo ru nipinlẹ  Ogun, ọrọ ti n di kolori dori ẹ mu.

Ọmọọba Rotimi Paṣẹda, ondije dupo gomina nipinlẹ Ogun labẹ SDP ni wọn kọkọ doju ọrọ ru mọ lọwọ lopin ọsẹ to kọja, nigba to gbe ipolongo rẹ lọ sagbegbe Ijẹbu, eyi toun naa jẹ ọmọ bibi ibẹ.

Ṣugbọn to jẹ bo ṣe fẹẹ bẹrẹ si i sọrọ lawọn janduku ya bo wọn, ni wọn ba bẹrẹ si i kọrin atako, ni wọn n darukọ ẹgbẹ oṣelu mi-in ti ki i ṣe ti Paṣẹda, ni wahala ba sọkalẹ pẹrẹwu.

 

Ẹsẹkẹsẹ lawọn alajangbila naa ti gba oju agbo mọ awọn Paṣẹda lọwọ, lo ba dohun tawọn eeyan n sa kijokijo kiri.  Kia ni wọn ti n ji awọn nnkan ironilagbara ti Paṣẹda fẹẹ pin fawọn eeyan gbe, awọn irinṣẹ bii maṣinni iranṣọ, firiiji, ẹrọ iṣẹrunloge, kuka ti wọn fi n dana atawọn nnkan mi-in, wọn ko gbogbo ẹ lọ.

Fun bii ogun iṣẹju ni oju agbo ipolongo fi daru, ọgbọn ni wọn fi gbe Paṣẹda funra ẹ atawọn to sun mọ ọn kuro nibẹ, ti awọn nnkan oloro tawọn eeyan naa n lo ko fi ṣe wọn lọṣẹ.

 

Ondije dupo labẹ SDP yii naa sọrọ, o loun mọ pe awọn alatako ti ẹru aṣeyọri oun n ba ni wọn wa nidii iwa janduku naa. Awọn ti wọn ko fẹ ki ipinlẹ Ogun bọ loko ẹru ni wọn n huwa ọta ilọsiwaju nibi ipolongo.

 

Bi ko ba jẹ bẹẹ, Paṣẹda ni ko sẹni to da oun lọna ri boun ba n polonogo ibo, ka ma ti i waa sọ n’Ijẹbu ti i ṣe ilu oun gan-an. Ana ode yii, Mọnde, lo ni oun yoo lọọ fiṣẹlẹ naa to Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, Iliyasu Ahmed, leti funra oun.

 

Bakan naa lọmọ ṣori nibi ipolongo ibo Ọmọọba Dapọ Abiọdun. Awọn kan la gbọ pe wọn de pẹlu mọto bọọsi Camry kan ti wọn ti fi nnkan bo nọmba idanimọ rẹ loju, ni wọn ba ṣina ibọn bolẹ fawọn alatilẹyin ondije dupo gomina lẹgbẹ APC naa. Wọn ni wọn yinbọn sawọn eeyan to fẹẹ pade Dapọ Abiọdun ni gareeji Odogbolu.

 

Akọwe ipolngo APC nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Tunde Ọladunjoye, lo fi atẹjade to ṣalaye ikọlu naa sita fawọn akọroyin lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii.

O ṣalaye pe awọn to wa ninu mọto alatako yii da nnkan boju ni, ko sẹni to ri oju wọn. Bi wọn ṣe ri ọlọpaa to maa n tẹlẹ ọkan lara

awọn eeyan Dapọ Abiọdun, iyẹn Ọgbẹni Owodunni Ọpẹyẹmi, ni wọn yinbọn lu ọlọpaa naa, to si ṣubu sinu agbara ẹjẹ.

Ẹẹkẹ ni ibọn ti ba agbofinro yii gẹgẹ bii alaye Ọladunjoye, niṣe ni wọn sare gbe e lọ sọsibitu Jẹnẹra Odogbolu, ṣugbọn titipa nibẹ wa, wọn ko ṣi i.  Bi wọn ṣe tun sare gbe e digbadiga lọ ṣọsibitu aladaani kan niyẹn, nibẹ ni wọn si ti bẹrẹ itọju fun un lẹsẹkẹsẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe oun ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa lasiko ta a n kọ iroyin lọwọ, awọn to ṣoju ẹ sọ pe ipolongo awọn oloṣelu mejeeji yii ko lọ nirọwọ-rọsẹ rara. Koda, wọn ko le pari eto naa mọ, nigba to ti di ẹni ori yọ o dile.

Ohun to ṣẹlẹ yii n kọ awọn eeyan lominu, ẹru si n ba ọpọ eeyan, paapaa lori idibo gomina nipinlẹ yii. Nitori bi jagidijagan ṣe gbode kan lasiko tibo ku si dẹdẹ yii ko ni itumọ meji ju pe ija agba yoo ṣẹlẹ laarin awọn ondije dupo naa lọ.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.