Awọn ọmọ ‘Yahoo’ meji tun rẹwọn ọdun kan he ni Kwara

Spread the love

Ajọ to n gbogun tiwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu, EFCC, ti tun ṣe aṣeyọri kan lori gbigbe ogun ti awọn to n lu jibiti lori ẹrọ ayelujara eyi tawọn eeyan mọ si ‘Yahoo’, pẹlu bawọn ọdọkunrin meji kan, Muhammed Faruk ati Abọlarin Ridwan, ṣe rẹwọn ọdun kan he.

Adajọ Sikiru Oyinloye ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara lo paṣẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, pe kawọn ọdaran mejeeji naa lọọ fẹwọn jura. 

Ọjọ kọkanla, oṣu keji, ọdun 2019, lọwọ tẹ awọn mejeeji lagbegbe Irewọlede, niluu Ilọrin, lẹyin tawọn eeyan ti ta EFCC lolobo pe irin awọn ọdaran ọhun ko mọ.

Faruk ni wọn fẹsun kan pe o n lo awọn orukọ oyinbo loriṣiriiṣi bii, Morgan Chase, Lina Swagger, Gina Crytal, Jeff Brad, Felicia Gonzales, Chase Big, lati maa fi lu awọn eeyan ni jibiti lori intanẹẹti.

Bakan naa ni ọdaran keji, Ridwan, n lo orukọ Frank Sinatra pẹlu foto oyinbo lati maa fi gba awọn to ba ko si pampẹ rẹ.

Awọn mejeeji ni wọn jẹwọ pe awọn jẹbi ẹsun tajọ EFCC fi kan wọn.

Adajọ Oyinloye to gbe idajọ rẹ kalẹ nile-ẹjọ gba gbogbo ẹri ti agbẹjọro EFCC, Sẹsan Ọla, gbe siwaju rẹ wọle, o si fi han pe ajọ naa ti fidi ẹsun ta a fi kan awọn ọdaran naa mulẹ.

“Fun idi eyi, awọn ọdaran naa jẹbi ẹsun ta a fi kan wọn, wọn yoo lọọ ṣẹwọn ọdun kan, bẹrẹ lati ọjọ kọkanla, oṣu keji, ọdun 2019. Gbogbo awọn foonu wọn atawọn ohun ini mi-in ti wọn feru ko jọ nijọba apapọ ti gbẹsẹ le.”

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.