Awọn ọmọ keekeeke meji to ji ẹrọ ata n’Ilupeju foju ba kootu

Spread the love

Awọn ọmọde meji kan, Muideen, ọmọ ọdun mọkandinlogun, ati Ayọbami, ọmọ ọdun mejidinlogun, ni wọn ti wọ lọ si kootu Majisreeti to wa ni Ikẹja, wọn ni wọn ji ẹrọ ilọta Honda meji tiye rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọfa Naira (N120,000.00).
Awọn afurasi naa ti wọn ko ni pato ibi ti wọn n gbe ni wọn fẹsun igbimọ-pọ huwa ọdaran ati ole jija kan. Awọn mejeeji si ni wọn ni awọn ko jẹbi awọn ẹsun naa.
Sajẹnti Micheal Unah to ṣoju ileeṣẹ ọlọpaa ni kootu sọ pe ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni awọn olujẹjọ huwa naa ni nnkan bii aago mẹta aarọ, ni ọja Temidire Fọlashade Tinubu Ojo to wa ni Ilupeju, niluu Eko.
O ni awọn ọmọ mejeeji naa gbimọ-pọ, wọn si wọ inu ọja naa lọna aitọ, nibi ti wọn ti ji ẹrọ ilọta Honda meji, eyi ti i ṣe ti Ọgbẹni Bọlaji Mukaila.
Ẹsun naa tako awọn abala kan ninu ofin to de iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko n lo, tọdun 2015.
Adajọ A.A Fashọla to gbọ ẹjọ naa faaye beeli silẹ fun wọn pẹlu
ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ati oniduuro meji niye kan naa.
O sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu yii.

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.