Awọn ọmọ Ibo to n jale l’Arigbajo bọ sọwọ ọlọpaa

Spread the love

Meji ninu awọn ọmọ Ibo ti wọn ni ole jija ni wọn mu niṣẹ l’Arigbajo, nitosi Ifọ, Ebuka Emezurike ati Chinonzo Ndiaba, ti bọ sọwọ ikọ ọlọpaa FSARS bayii.

Ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan-an, ni ifisun de etiigbọ awọn ọlọpaa FSARS, pe awọn adigunjale kan n daamu awọn olugbe Itori si Ewekoro, wọn ko si yọ Arigbajo naa silẹ rara.

Wọn ni pẹlu nnkan ija ni wọn maa n wọle awọn eeyan, ti wọn yoo ja wọn lole, ti wọn yoo si tun ṣe awọn mi-in leṣe.

Iwadii awọn ọlọpaa lo jẹ ki wọn mọ pe Arigbajo gan-an nibi tawọn ole naa fi ṣe ibuba, wọn kan maa n lọ sawọn ilu meji to ku lati ṣọṣẹ ni.

Ikọ FSARS ti ASP Ayuba Peter n dari ṣawari ibudo awọn ole naa loṣu to kọja yii, ọwọ si ba Ebuka ati Chinonzo, nigba ti awọn yooku wọn sa lọ.

Nigba ti wọn n jẹwo ẹṣẹ wọn siwaju si i f’ALAROYE, awọn ọkunrin meji ti ọjọ ori wọn jẹ mẹrindinlọgbọn ati mẹrinlelogun naa sọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wọn n pe ni ‘Norsehoeseman’ lawọn.

Wọn ni yatọ si pe kawọn ja awọn eeyan lole pẹlu nnkan ija, awọn tun maa n na ayederu owo fawọn ọlọja, awọn yoo si tun gba ṣenji pẹlu, nitori ẹgbẹrun kan Naira ni ayederu owo tawọn saba maa n na.

Nipa bi wọn ṣe n ri owo yii, Ebuka to ni oun tun n ṣiṣẹ nileeṣẹ awọn Ṣainiisi kan l’Ewekoro, ṣalaye pe ẹgbẹrun marundinlogoji Naira ni wọn n san foun loṣu. O ni ṣugbọn owo naa ki i to oun i na toṣu ba maa fi pari, iyẹn loun ṣe maa n lọọ ra ayederu owo naa lọdọ awọn mọla kan.

O ni ẹgbẹrun marun-un Naira to jẹ owo gidi loun maa n fun wọn, ti wọn yoo si foun ni ẹgbẹrun mẹwaa to jẹ ayederu. Igba mi-in, o si le ju bẹẹ lọ, boun ba  ṣe fun wọn lojulowo owo to ni ayederu ti wọn yoo foun yoo ṣẹ pọ to.

Awọn owo naa lo ni oun ati Chinonzo tawọn jọ n gbe maa n na lọwọ ale fawọn ọlọja ti ko ba fura.

Nipa ẹgbẹ okunkun ti wọn wa, wọn ni ki i ṣe pe awọn maa n paayan bẹẹ yẹn naa, bi iṣẹ ba gba bẹẹ ni. Ebuka tilẹ sọ pe iṣẹ awọn ọga awọn ninu ẹgbẹ naa niyẹn. Awọn ohun to jẹ ere tawọn ni pe wọn maa n fun awọn ni irinṣẹ tawọn yoo fi jale bii ibọn, ada atawọn nnkan mi-in bẹẹ.

O ni kawọn ọlọpaa too waa mu awọn yii gan-an ni olobo ti ta oun naa pe aṣiri ti tu, ati pe awọn ọlọpaa ti n wa awọn kiri. Ebuka sọ pe ikeji oun ti i ṣe Chinonzo loun ni koun waa sọ fun pe ko jẹ kawọn sa kuro nipinlẹ Ogun, ṣugbọn nibi toun ti waa sọrọ naa fun un lawọn ọlọpaa ti de, ti wọn si mu awọn.

Ibọn ilewọ, oogun ibilẹ, ami idanimọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n ṣe atawọn ayederu ẹgbẹrun kan Naira lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ awọn eeyan yii.

Ọga agba ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Iliyasu Ahmed, ti ni kootu ni wọn yoo pari ọrọ wọn si laipẹ, ibẹ ni wọn yoo si gba lọ si ọgba ẹwọn taara.

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.