Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun pa ara wọn sile ọti n’Ileṣa Bisi Adesoye

Spread the love

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹta kan, Abu, Ige ati Dare ku sile ọti, nibi ti wọn ti n ba ara wọn ja nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ileṣa.

Gẹgẹ bi ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ loju ẹ to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ṣe sọ, o ni Abu ati Ige ni wọn jọ n ṣe faaji nile ọti kan ni adugbo Iboṣinrin lojo naa, ki awọn eeyan si too mọ nnkan to n ṣẹlẹ, ija ti bẹ silẹ nile-ọti ọhun, wọn si ti bẹrẹ si i yinbọn funra wọn. Nibi ija yii ni Abu ati Ige ku si.

Ẹni ti ọrọ yii ṣoju ẹ ni ija naa ko pari lọjọ Sannde yii, wọn ja a titi wọ ọjọ Aje, Mọnde ni. Ti ọjọ Mọnde yii si ni wọn fi pa Dare si Egbeedi, ti ko fi bẹẹ jinna si Iboṣinrin, ti wọn pa awọn ọkunrin mejeeji akọkọ si.

Nigba ti ALAROYE n ba agbẹnusọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, DSP Fọlaṣade Odoro, sọrọ, o ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori iku awọn ọmọkunrin naa, awọn si ti mu awọn janduku kan ti wọn n ran awọn lọwọ lati mọ ohun to fa ija wọn.

(37)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.