Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye da adugbo ru l’Ọta, wọn ti foju bale-ẹjọ

Spread the love

Eeyan meje ti wọn ni ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye ni wọn foju ba kootu Majisireeti to wa niluu Ọta, nipinlẹ Ogun, lọjọ Aje to kọja yii. Wọn ni wọn fi nnkan ija oloro dẹru ba awọn ara adugbo, wọn si da ibẹrubojo silẹ lọsan-an gangan.

Awọn meje naa ni: Shobande Akeem, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Sunday David, ẹni ọdun mejilelọgbọn, Quwin Jese, ọmọ ọdun mọkanlelogun, Ismail Raheem, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, Abiọdun Ajifọlawẹ, ẹni ọdun mẹẹẹdogun, Ibrahim Adetunji toun naa jẹ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ati Ṣẹgun Adeọla, eni ọdun mẹtalelọgbọn.

Gẹgẹ bi ọlọpaa to ṣoju ijọba ni kootu, Abdulkareem Mustpha ṣe sọ, o ni ọgbọnjọ, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni awọn eeyan naa da wahala silẹ, laago mẹrin aabọ irolẹ, ti wọn bẹrẹ si i da agbegbe ile ọba tẹlẹ niluu Ọta, (Old palace road) ru, to jẹ bi wọn ṣe n pago mọlẹ ni wọn n yọ ọbẹ, ti kaluku wa n sa kijokijo kiri.

Ẹsun keji ti wọn tun ka si wọn lẹsẹ ni jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun, ẹgbẹ Aiye. Agbefọba ṣalaye pe ẹsun mejeeji lo lodi sofin ninu iwe ofin ipinlẹ Ogun, ijiya si wa fun un.

Nigba ti wọn n fesi si ibeere kootu pe ṣe wọn jẹbi tabi bẹẹ kọ, awọn olujẹjọ naa ni awọn ko jẹbi.

Adajọ agba Matthew Akinyẹmi to gbọ ẹjọ naa faaye beeli silẹ fun wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun (300,000), Naira ẹnikọọkan, pẹlu oniduuro meji-meji.

Ai ri oniduuro fun wọn lo sọ wọn di ero atimọle, ibẹ ni wọn yoo si wa titi di ọjọ keje, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ.

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.