Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC fipa bara wọn sun n’Ileṣa

Spread the love

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kan, Adeyẹmi Fatoke, lo fipa ba ọmọ ẹgbẹ rẹ, Arabinrin Bọlanle Ayọdele, lo pọ lẹyin ti wọn pari ipolongo ibo l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to lọ lọhun-un niluu Ileṣa.

Ohun ta a ri gbọ lẹnu Ọgbẹni Agboọla to fi ọrọ naa to wa leti ni pe lẹyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ṣe ipolongo ibo tan ni wọn ko ara wọn lọ sileetura kan n’Ileṣa, lati lọọ sinmi nirọlẹ ọjọ naa. Nibi ti wọn ti n sinmi yii ni Adeyẹmi ti bu nnkan sinu ọti bia ti Bọlanle n mu, ko si pẹ sigba naa lo bẹrẹ si i toogbe, ti ko mọ nnkan to n ṣe mọ.

Pẹlu bi arabinrin yii ti n toogbe ni Adeyẹmi fi mu obinrin adelebọ yii wọnu yara kan ninu ile-itura yii, to si fipa ba a sun nibẹ.

Gbogbo bo ti n gbiyanju lati ba obinrin yii sun ni o n sọ fun un pe oun wa ninu oyun oṣu mẹta, sibẹ Fatoke ko gbọ, o ba obinrin naa sun titi to fi bẹrẹ si i ri ẹjẹ ni.

Ẹjẹ to ri yii lo ba a lẹru to fi sare gbe ọmọbinrin naa lọ sileewosan Wesley ti wọn ti n tọju ẹ. Nitori ko ma baa lọọ sọ fun awọn ọlọpaa, Adeyẹmi gba lati sanwo itọju ọmọbinrin naa, bẹẹ lo san ẹgbẹrun mẹwaa gẹgẹ bii owo itanran fun ohun to ṣe.

Bọlanle kọ ọkọ rẹ silẹ nitori ko fun un nitọju to peye, oun lo si n da tọ awọn ọmọ meji to bi fun ọkunrin naa, eyi lo sọ ọ di oloṣelu ọsan gangan, to jẹ tọrọ-kọbọ to n gba bọ nibi ipolongo yii lo fi n tọju awọn ọmọ mejeeji naa.

Titi di asiko ti a n ṣakojọpọ iroyin yii, Bọlanle ṣi wa nileewosan Wesley ti wọn ti n tọju rẹ ki nnkan ma baa ṣe oyun oṣu mẹta to wa ninu ẹ.

 

 

 

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.