Awọn ọmọ Buhari da, ẹ jade sita o

Spread the love

Bi gbogbo eeyan pariwo pe Aarẹ Muhammadu Buhari ko dara gẹgẹ bii olori orilẹ-ede yii, igba rẹ ko sunwọn ati bẹẹ bẹẹ lọ, awọn kan wa ti wọn ko ni i gba, to jẹ wọn le tori ọrọ naa fori sọ ẹni to ba n sọ ọ laya, ti wọn yoo si binu da gbogob nnkan ru. Ohun ti wọn maa n tẹnumọ ni pe ko si ẹni to tun le ri biiBuhari, wọn aa ni oloootọ ati olododo gbaa ni, ẹni to ṣee fọkan tan, ẹni ti ki i ko owo jẹ, ti ko si ni i jale nile-ijọba laelae, Wọn aa ni nitori iwa ibajẹ ti ko si lọwọrẹ yẹn gan-an lawọn ṣe fẹran rẹ. Nidii eyi, ko si ohun to n gbe Buhari niyi ju iwa ibajẹ ti ọpọlọpọ awọn eeyan nilẹ yii nigbagbọ pe ko si lọwọ rẹ lọ. Ṣugbọn awọn ọrọ kan jade lọsẹ to kọja yii, awọn ọrọ to le ba orukọ Buhari jẹ ati awọn ohun gbogbo ti wọn fi n pọn ọn le ni. Iyẹn loun naa ṣe gbọdọ jade ko sọrọ, awọn ọmọlẹyin rẹ gbọdọ tete jade, ọrọ naa ki i ṣe eyi ti wọn yoo fi ọwọ bi danu pe ko to nnkan, ọrọ ti aarẹ gbọdọ tete sọ si ni. Awọn ọmọọṣẹ Atiku kan niwọn fi ẹsun kan aarẹ, wọn ni awọn ileeṣẹ meji kan wa ti wọn ti dẹnukọle ti ijọba si ta nitakuta, ṣugbọn abalọ-ababọ, o ti han pe awọn ẹbi Buhari ni wọn ra awọn ileeṣẹ naa, owo buruku ti wọn si ra wọn n lọ si bii Triliọnu kan, o tun le. Owo ti wọn n pe ni Triliọnu yii ko daa, owo rẹpẹtẹ ti ko ṣee sọ tan ni, nitoribiliọnu lọna ẹgbẹrun kan ni wọn n pe bẹẹ, bẹẹ miliọnu lọna miliọnu kan ni biliọnu funra rẹ. Ṣugbọn owo naa ni wọn ni awọn Buhari ko kalẹ lati fi ra banki kan ti wọn pe ni Keynote Bank ati ileeṣẹ GSM Etisalat. Ko gbọdọ jẹ bẹẹ lawọn eeyan kan n wi. Ko tiẹ gbọdọ jẹ bẹẹ rara. Idi ni pe nibo ni ki Buhari ti ni oun ti ri owo to to bẹẹ, nibo lawọn eeyan rẹ yoo sọ pe awọn ti ri owo to to bẹẹ. Tabi ki iṣe Buhari ti awọn eeyan n da owo jọ fun lati fi ra fọọmu idibo lọdun mẹrin sẹyin ree nitori wọn ni ko sowo lọwọ rẹ ti yoo fi ra a. Nibo ni ki wọn waa sọ pe awọn ti ri iru owo buruku bayii. Dajudaju, owo yoowu ti wọn ba ri bẹẹ yẹn ki i ṣe owo mimọ, owo ole ni. Tabi iṣẹ wo leeyan yoo ṣe laarin ọdun mẹrin ti yoo ri Triliọnu kan, ko si iru iṣẹ bẹẹ nilẹ yii rara. Ohun ti Buhari ṣe gbọdọ sọrọ niyi, bẹẹ ni awọn ileeṣẹ mejeeji gbọdọ ṣe atẹjade awọn darẹkitọ ti wọn ni ileeṣẹ naa sita fun gbogbo ọmọ Naijiria, ki kaluku le mọ boya awọn Buhari ti ra wọn tabi irọ ni. A n jẹ ekuru ko tan, awọn kan tun n gbọn ọwọ rẹ sinu awo, ọrọ Naijiria yii ti fẹẹdi wahala debii pe bi wahala kan ti n lọ ni omi-in n de. Ṣe Buhari lo ra Etisalat?Ṣe oun ati awọn eeyan rẹ ni wọn ra Keystones Bank? Gbogbo ọmọ Naijiria lo fẹẹ mọ o. Buhari gbọdọ sọrọ naa jade sita gbangba.

 

 

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.