Awọn oludije fun ipo gomina n pọ si i ninu ẹgbẹ oṣelu PDP

Spread the love

Lọsẹ to kọja yii ni Abẹnugan ile-igbimọ aṣofin Kwara tẹlẹ, Rasak Atunwa, gba fọọmu lati dije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.

Atunwa, to n ṣoju ẹkun Iwọ-Oorun Ilọrin ati Asa nile igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, lo maa jẹ oludije karun-un to fifẹ han lati dupo gomina ipinlẹ Kwara labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Awọn mi-in to tun fifẹ han ni; minisita tẹlẹ fun ere idaraya, Mallam Bọlaji Abdullahi; Abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara, Dokita Ali Ahmad; Ọmọ ile-igbimọ aṣoju-ṣofin, Zakari Mohammed, Alhaji Ladi Hassan atawọn mi-in.

Atunwa to gba fọọmu rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, ni olu-ile ẹgbẹ PDP l’Abuja, ni ireti wa pe yoo bẹrẹ si i jẹ ki awọn eeyan mọ nipa erongba rẹ yii laipẹ.

Bakan naa, ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni minisita tẹlẹ fun idagbasoke ere idaraya l’orilẹ-ede Naijiria, Mallam Bọlaji Abdullahi, kede pe oun naa fẹẹ dupo gomina ipinlẹ Kwara lọdun to n bọ.

Lara awọn to ṣatilẹyin fun Abdullahi ni Akọwe ijọba ipinlẹ Kwara,  Alhaji Isiaka Gold, Oluranlọwọ pataki Gomina Ahmed ni ẹka iroyin, Akorede, ati awọn alaṣẹ ijọba mi-in.

Gbajumọ oṣere ọmọ bibi ilu Ilọrin nni, Fẹmi Adebayọ, ti awọn eeyan tun mọ si ‘Jẹlili’ naa kọwọọrin pẹlu Bọlaji Abdullahi lati fi atilẹyin rẹ han si i.

Ikede ọhun to waye ninu gbọngan nla Arca Santa, to wa lọna Ajaṣẹ-Ipo, niluu Ilọrin, ni awọn alatilẹyin Bọlaji Abdullahi pe jọ si.

Ọkunrinto ti figba kan jẹ minisita yii sọ pe ohun to jẹ oun logun ju ti oun ba ni anfaani lati de ipo gomina ni ironilagbara fun awọn ọdọ. O ni o maa jẹ ohun to n ba ni lọkan jẹ lati maa ri awọn ọdọ to n rin kaakiri ti wọn si n ṣe ohun to lodi si ofin nitori ti wọn ko ni iṣẹ lọwọ.

Abdullahi sọ pe ipese iṣẹ fawọn ọdọ yii lo maa jẹ nnkan gboogi ninu iṣejọba oun.

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.