Awọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC mẹsan-an darapọ mọ ẹgbẹ ADP l’Ọṣun Wọn ni bi wọn ṣe yan Oyetọla ko tẹ awọn lọrun

Spread the love

Mẹsan-an ninu awọn to lẹnu ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), nipinlẹ Ọṣun, ni wọn ti kuro ninu ẹgbẹ naa bayii, ti wọn si ti darapọ mọ ẹgbẹ Action Democratic Party (ADP). Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ninu lẹta kan ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa kọ lọjọ kẹfa, oṣu yii, eyi ti wọn fi ṣọwọ si alaga ẹgbẹ naa ni wọn ti sọ eleyii di mimọ.

Awọn to kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni: Azeez Isa Adeṣiji, ti i ṣe igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu naa nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ileṣa, Tajudeen Agbeti, lati ijọba ibilẹ Iwo-Oorun Ileṣa, Ademọla Bamidele, ti i ṣe ayẹwe-owo wo ẹgbẹ naa tẹlẹ lati ijọba ibilẹ Ifẹlodun, Rasheed Bakare, atawọn oloye ẹgbẹ mi-in.

Lara ẹsun ti awọn to ya kuro yii fi kan ẹgbẹ wọn ni pe awọn ko faramọ ọna ti wọn gba yan Alhaji Isiaka Oyetọla gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije-dupo gomina lorukọ ẹgbẹ oṣelu naa ninu eto idibo si ipo gomina ti yoo waye nipinlẹ Ọṣun laipẹ.

Bakan naa, ni wọn fẹsun kan igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ, eyi ti Ọmọọba Adegboyega Famọdun n tukọ rẹ pe ko ko akoyawọ to, to si jẹ pe niṣe lo n gbe lẹyin awọn kan ti wọn fẹ maa jẹ gaba le awọn ọmọ-ẹgbẹ yooku lori.

Ṣugbọn ṣa, alukoro ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, Kunle Ọyatomi, sọ pe oun ko gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ kankan fi ẹgbẹ APC silẹ. O ṣalaye pe ẹgbẹ ADP ti awọn eeyan naa n lọ ki i ṣe ẹgbẹ to lẹnu ninu eto iṣelu nipinlẹ Ọṣun.

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.