Awon oloye egbe APC Ondo n binu si awon oloye apapo l’Abuja

Spread the love

Bi awon asaaju egbe oselu APC apapo ko ba tete wa nnkan se lati petu si awon omo egbe naa nipinle Ondo ninu, o see se ki whala nla sele. Idi ni pe inu awon eeyan naa ko dun si bi won se ni awon asaaju egbe lati ilu Abuja, paapaa julo, alaga egbe won, Adams Oshiomhole  se gbe awon oloselu kan le won lori, ti won ko si faaye ibo abele sile lati waye.

Awon seneto to n soju aown eeyan naa nile igbomo asofin bayii ni awon asaaju egbe fun ni tileeti lati dije dupo lai ni atako, ti won ko si fi anfaani sile fun ibo abele.

Awon oloselu toro kan ni Ajayi Boroface to wa lati  North(please translate) , Ogbeni Yele Omogunwa to wa lati South ati Tayo Alasoadura to wa lati Aarin-Gbungbun, nipinle Ondo. Awon meteeta yii ni egbe fun ni tikeeti. Eyi lo mu ki aown oloye egbe naa nipinle Ondo, to fi mo gomina won, Ogbeni Rotimi Akeredolu maa pariwo pe afi ki won gba a lowo won, ki won si fun awon ti egbe dibo yan lasiko eto idibo abele ni anfaani si ipo naa.

Se ni ojo Eti, Furaidee, ose to lo lohun-un ni egbe naa dibo abele won, nibi ti awon omo egbe ti yan Dokita Tunji Abayomi(North), Seneto Tayo Alasoadura, (Central) , ati Onorebu Lucky Aiyedatiwa (South).

Alaga egbe naa, Ogbeni Adetimehin waa ni niwon igba tawon ti tele ase ti egbe la kale pelu bi awon se lo ilana eto idibo abele ti o ba ofin egbe mu, nise lo ye ki won kede awon awon ti egbe dibo yan naa gege bii awon ti yoo soju won lasiko idibo odun to n bo.

O ni ko ye ki awon agbaagba se ojusaaju lori eleyii.

 

Aaya be sile o be si are ni bayi, leyin ti aown egbe oselu kookan ti yan asoju won, eto ipilongo ibo lo ku ti yoo bere ni peru kaakiri ipinle nile Naijiria, nibi ti egbe kookan yoo ti koju awon alatako won ninu eto idibo odun to n bo.

 

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.