Awọn ọlọpaa yinbọn pa olori ọmo ẹgbẹ okunkun l’Ekoo

Spread the love

Afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Ọlamide Ọlọruntobi, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, ti wọn furasi pe oun ni olori ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye, ni awọn ọlọpaa ti ṣeku pa ni  Iṣhashi, Ọjọ, niluu Eko. Adugbo Duroṣootọ, Celenizer, New Mebamu, ni wọn pa a si, ni nnkan bii aago mẹsan-an ku iṣẹju mẹwaa. Wọn ni lasiko ti Ọlamide n ko awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ sodi lati da omi alaafi agbegbe naa ru ni iroyin kan ọga ọlọpaa teṣan Ishashi, Amuda Abọlaji, lara, ẹni to ko awọn ọmọ rẹ sodi lọ sibẹ.

Nigba ti wọn de ibẹ ni awọn ọlọpaa pẹlu awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun naa doju ibọn kọra wọn, lasiko naa si ni Ọlọruntobi ku.

Chike Oti ti i ṣe Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko fidi isẹlẹ yii mulẹ. O sọ pe awọn ri ibọn agbelẹrọ kan lọwo Tobi, awọn si ti gbe oku rẹ lọ si Ọsibitu Jẹnẹra ni Badagry, fun ayẹwo.  O fi kun un pe Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, ti paṣẹ fun ọga ọlọpaa ni tesan naa lati ṣawari awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yooku to sa lọ naa.

(22)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.