Awọn ọlọpaa ti fi Dino Melaye silẹ

Spread the love

Fun bii wakati meji abọ ni Sẹnetọ Dino Melaye to n ṣoju ẹkun Kogi nile igbimọ aṣofin niluu Abuja lo lọdọ awọn ajọ to n risi wọle wọde lana an Monde nigba tawọn yẹn muu pe aṣẹ wa lati ọdọ awọn ọlọpaa pe wọn n wa.
Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, papakọ ofurufu ti Nnamdi Azikwe lọwọ ti tẹ ọkunrin naa lakooko to fẹẹ rin irinajo lọ si orilẹ-ede Morocco.
Ninu atẹjade ti ọkunrin naa ti kọkọ fi sita lakooko ti wọn mu un, o sọ pe irinajo ijọba apapọ kan lawọn n lọ fun ni Morocco pẹlu igbakeji olori ile igbimo aṣofin atawọn aṣofin mi-in. O ni bawọn kan ṣe pinnu lati gba Eko lọ ni oni, bẹẹ lawọn kan lọ ni ana lati Abuja.
Dino Melaye ni, ”Bi mo ṣe de papakọ ofurufu ni wọn ti yẹ mi wo, ti mo si ti jokoo, ti a n reti ki baalu wa gbera, ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ wọle wọde waa ba mi pe awọn gba aṣẹ lati ọdọ ọlọpaa pe mi o le rin irinajo, o ni wọn n wa mi.”
O loun sọ fun wọn pe irọ ni wọn n pa, pe oun ko ri iwe kankan tabi aṣẹ kankan pe wọn n wa oun, o loun fi ẹrọ ayelujara oun han wọn, ṣugbon ṣe lo ni wọn sọ pe dandan, aṣẹ ti wa latọdọ awọn ọlọpaa.
Dino tun sọ pe ṣe ni wọn ni ki oun tẹle wọn de ọfiisi, ko si pẹ ni wọn ja iwe irinajo oun gba, toun si ja a gba pada lọwọ wọn. O nibẹ loun ṣi wa nigba naa ti wọn sọ pe awọn n reti aṣẹ mi-in lati ọdọ awọn ọlọpaa.
A o ranti pe loṣu to kọja ni Ọgbẹni Ali Janga to jẹ kọmiṣanna awọn ọlọpaa kede pe awọn n wa Dino Melaye.

(40)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.