Awọn olopaa ti bere iwadii lori dereba tawon ero lu pa l’Oshodi

Spread the love

Bo tilẹ jẹ pe ọwọ awọn ti tẹ ọpọlọpọ eeyan bawọn ero inu ọkọ ṣe pa dẹrẹba bọọsi kan, sibẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Chike Oti, ti sọ pe iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.

Ṣe laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja ni awọn eeyan kan lu dẹrẹba naa pa, nigba ti wọn ni oun naa gun ero inu bọọsi yii kan ti wọn ko mọ orukọ rẹ lọbẹ pa laduugbo Five Star, lọna marosẹ Oshodi si Apapa.

Wọn ni ṣe ni dẹrẹba yii sọ fun awọn ero to gbe pe oun ko le lọ si Oshodi mọ, to si ni oun aa ja wọn si adugbo Aswani. Ọrọ yii lo di wahala laarin oun ati awọn ero, to fi di pe o gun ẹnikan ninu wọn.

Lẹsẹkẹsẹ ni wọn ni dẹrẹba yii sa lọ, ko too di pe ọwọ pada tẹ ẹ  laduugbo Five Star. Nigba ti awọn eeyan le ba tan ni wọn bẹrẹ si i lu oun pẹlu kọndọkitọ rẹ, ṣugbọn kọndọkitọ naa raaye sa lọ. Ibinu iṣẹlẹ yii ni wọn fi dana sun awakọ naa, to si jẹ pe ṣe ni wọn ni wọn sọ awọn ọlọpaa to fẹẹ waa doola rẹ lokuta.

Oti sọ pe awọn ri ẹmi kọndọkitọ naa gba, bẹẹ lo ni iwadii awọn fihan pe wahala ṣẹlẹ nigba ti dẹrẹba naa sọ fun awọn ero inu ọkọ rẹ pe oun ko lọ si Oshodi mọ. O ni awakọ naa bẹ awọn ero yii, o si gba lati da owo ọkọ wọn pada, ṣugbọn awọn kan ninu wọn ni awọn ko fẹ owo, ko gbe awọn de ibi ti awọn n lọ ni.

Ọrọ naa lo di wahala, to fi di pe awọn ọmọ ita kan da si i, ti wọn si dana sun awakọ ati kọndọkitọ rẹ. O ni ina jo dẹrẹba naa gan-an, awọn si gbe e lọ si Ọsibitu Ẹkọṣẹ Iṣegun LUTH, nibi ti awọn dokita ti fidi ẹ mulẹ pe o ti ku.

Oti ni ọlọpaa mẹta lo faragba nibi iṣẹlẹ naa lasiko ti wọn n gbiyanju lati doola ẹmi dẹrẹba yii, ti wọn si tun fọ gilaasi ọkọ wọn.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.