Awọn ọlọpaa n wa awọn to pa dẹrẹba l’Ado-Ekiti

Spread the love

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti bẹrẹ iwadii lori awọn kan ti wọn fura si bii adigunjale ti wọn ṣeku pa ọkunrin kan niwaju garaaji Tosin Aluko to wa l’Ajilosun, niluu Ado-Ekiti, laaarọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja.

Lopin ọsẹ to kọja ni DSP Caleb Ikechukwu to jẹ alukoro ọlọpaa Ekiti ṣalaye fun ALAROYE pe ni kete ti iroyin iṣẹlẹ naa de ọdọ awọn agbofinro teṣan Ọlọgẹdẹ, lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii.

Ẹnikan to kọ lati darukọ rẹ sọ pe ni nnkan bii aago mẹfa aabọ idaji niṣẹlẹ ọhun waye, nigba tawọn kan deede kọlu mọto oloogbe naa lati ẹyin, bo si ṣe sọkalẹ lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ lawọn yẹn yinbọn fun un ni ori ati ikun.

Gẹgẹ bi ẹni naa ṣe sọ, o ni bi awọn ẹruuku yii ṣe ṣiṣẹ ọwọ wọn tan ni wọn gbe mọto ti wọn n gbe bọ silẹ, ti wọn si gba omi-in pẹlu ibọn, eyi to fi wọn han bii adigunjale to lọọ ṣiṣẹ ibi nibi kan.

Bakan naa la gbọ pe awọn onimọto atawọn mi-in to wa nibi iṣẹlẹ yii ko duro wo ibi tọrọ ja si ti onikaluku fi sa asala fun ẹmi rẹ.

Lasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii, ko sẹni to ti i mọ oloogbe naa tabi ibi to ti wa, awọn ọlọpaa si ti gbe e lọ si mọṣuari ileewosan Ekiti State University Teaching Hospital, l’Ado-Ekiti.

 

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.