Awọn ọlọpaa n ṣewadii agbofinro to fibọn da wahala silẹ l’Ekiti

Spread the love

Ado-Ekiti ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ekiti lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, laimọ pe ọkunrin agbofinro kan tọwọ ti tẹ bayii lo deede yinbọn, to si da wahala nla silẹ.

 

Laaarọ ọjọ naa, ni nnkan bii aago mẹwaa, ni wahala bẹrẹ, nigba ti ibọn deede dun lagbegbe Titi di asiko yii lawọn kan ṣi n ro pe loootọ lawọn adigunjale wa siluu Old Garage, lawọn eeyan ba bẹrẹ si i sa kijokijo. Ṣe ni Ọja Ọba, Ijigbo, Ajilosun, Okeyinmi atawọn agbegbe to sun mọ wọn daru pẹlu bi awọn to ni mọto ṣe bẹ silẹ, ti wọn ba ẹsẹ wọn sọrọ, tawọn ọlọkada gan-an ko duro wo ero ti wọn gbe ti wọn fi ju ọkada silẹ, ti wọn gbe ere da si i.

 

Iroyin to bẹrẹ si i tan ka ni pe awọn adigunjale ọhun ti kuro ni Old Garage, wọn ti lọ si Bank Road, nibi tawọn ileefowopamọ pọ si. Ko pẹ rara tawọn ọlọpaa fi ya bo agbegbe naa, ṣugbọn wọn ko ri awọn to fẹẹ digunjale, iyẹn lo jẹ ki wọn wadii nnkan to fa rogbodiyan naa.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lopin ọsẹ to kọja, DSP Caleb Ikechukwu ṣalaye pe awọn n ba iwadii lọ lori agbofinro to huwa naa. Gẹgẹ bo ṣe sọ, ṣe lafurasi naa deede pariwo pe awọn adigunjale ti de o, lo ba tun yin ibọn AK47 to wa lọwọ ẹ, eyi to jẹ kọrọ naa jọ ootọ.

 

Ikechukwu waa sọ pe awọn yoo mọ idi ti agbofinro naa fi huwa ọhun nitori iru nnkan bẹẹ ti da ilu ru bayii. O fi asiko naa sọ fawọn araalu pe ko si nnkan to jọ iṣẹlẹ idigunjale, ati pe awọn n ṣiṣẹ takuntakun lati daabo bo ẹmi ati dukia nipinlẹ Ekiti.

 

Ṣe lọjọ Aje, Mọnde, to kọja lawọn adigunjale kan ya bo banki Access to wa niluu Ijero, nijọba ibilẹ Ijero, nibi ti wọn ti ṣeku pa ọlọpaa mẹta ati araalu kan.

ALAROYE gbọ pe ilu Ile-Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun, lawọn ẹruuku naa kọkọ lọ, ṣugbọn wọn ko raaye ṣiṣẹ laabi wọn pẹlu bi awọn ẹṣọ ibilẹ to wa niluu naa ṣe le wọn danu.

 

Ọkọ ambulansi ati posi la gbọ pe wọn ko ibọn atawọn ado abugbamu si ti wọn fi raaye wọ Ekiti ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ, ni wọn ba kọlu banki naa, wọn si pada ri ọna sa lọ.

 

Tẹ o ba gbagbe, idigunjale kẹrin ti yoo waye lawọn banki ipinlẹ Ekiti laarin ọdun yii niyi pẹlu bi wọn ṣe kọkọ kọlu Ileefowopamọ First Bank, ilu Ifaki-Ekiti, loṣu kẹrin, Union Bank, ilu Ilawẹ Ekiti, loṣu karun-un ati Union Bank, ilu Igede, loṣu kẹsan-an.

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.