Awọn ọlọpaa mu Damilare, wọn lo digunjale, o tun paayan l’Ekoo

Spread the love

Afurasi adigunjale kan, Damilare Adegbayibi, pẹlu awọn ikọ rẹ mẹrin mi-in ti wọn ni wọn n digunjale, bẹẹ ni wọn tun n paayan niluu Eko ni wọn ti mu bayii.

Adugbo Agege, ni wọn ni wọn ti huwa naa, awọn ọlọpaa to si de ibi iṣẹlẹ yii lasiko ti wọn n ṣiṣẹ ibi naa lọwọ lo le Damilare lere tọwọ wọn fi tẹ ẹ. Ọkunrin naa lo waa ṣe atọna bi ọwọ ṣe tẹ awọn afurasi yooku, iyẹn Ọjẹṣọla Ọṣundairo, Bashiru Suleiman, Rasak Ọṣunmade ati Haruna Ibrahim.

Iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fi han pe Damilare pẹlu awọn ikọ rẹ yooku ti ṣeku pa ọkunrin meji kan, Alawiya ati Ibrahim Akinbumi.

Atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa fi sita ṣalaye pe ni nnkan bii aago kan oru ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu to kọja, ni iroyin tẹ ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ pe awọn adigunjale kan n ṣọṣẹ lọna Adewumi Adebisi, l’Agege. Kiakia ni awọn ọlọpaa teṣan Dọpẹmu pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ti Ikẹja si gbe igbesẹ. Bi awọn ẹlẹgiri naa ṣe foju kan wọn ni wọn fẹẹ maa sa lọ, ṣugbọn awọn naa gba ti wọn, lasiko naa lọwọ si tẹ Damilare Adegbayibi. Wọn ka ibọn ilewọ kan ati ibọn ṣakabula kan mọ ọn lọwọ. Nigba ti awọn ọlọpaa tun maa ṣiju soke, niṣe ni wọn ri oku awọn eeyan meji nibi iṣẹlẹ yii, eyi ti ayẹwo si fi han pe wọn gun wọn lọbẹ pa ni. Ọkan ninu awọn ti wọn pa ni ọkunrin kan ti awọn ọlọpaa pe orukọ rẹ ni Alawiya, ti wọn ko ti i mọ orukọ mọlẹbi rẹ titi di asiko yii. Alawiya ni wọn lo n ṣiṣẹ ọdẹ lagbegbe yii, ẹni keji to si ba ikọlu awọn adigunjale yii rin ni Ibrahim Akinbumi, olugbe agbegbe Adewumi Adebisi, l’Agege, niluu Eko.

Adegbayibi lo pada waa mu awọn ọlọpaa lọ si ibi ti wọn ti mu awọn afurasi mẹrin to ku. Awọn ọlọpaa ṣewadii siwaju si i pe ọkada ni awọn ikọ adigunjale yii fẹran lati maa ji gbe. Ẹni ti wọn maa n ta awọn ọkada naa fun ni Ibrahim Haruna, Edgal si ni lẹyin iwadii awọn, ileeṣẹ ọlọpaa yoo ko awọn afurasi naa lọ si kootu.

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.