Awọn ọlọpaa mu adigunjale to n lo iboju

Spread the love

Ọlọpaa ipinlẹ Eko, ti mu ọkunrin kan, Ahmed Saliu, ẹni ọdun mọkanlelogun to maa n lo iboju, eyi to fi maa n ja awọn ara ọja lole niluu Eko.
Ọja Odo-ẹran to wa ni Oworonṣhoki ni wọn ni o ti n ja awọn eeyan lole pẹlu aṣọ iboju lọsan-an gangan.
Gẹgẹ bi atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Chike Oti, fi sita, o sọ pe Saliu atawọn ikọ adigunjale rẹ ni wọn wọ aṣọ iboju, ti wọn si fọ awọn ṣọọbu to wa lọja naa lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu to kọja.
Lasiko ti wọn n ṣiṣẹ naa lọwọ ni iroyin tẹ ọga ọlọpaa teṣan Oworonṣhoki lọwọ, oun lo si ko awọn ọlọpaa sodi lọ sibi ti ọwọ ti tẹ ọmọkunrin naa. Nigba ti awọn ole naa ri awọn ọlọpaa ni wọn sa lọ, ṣugbọn ọwọ pada tẹ Saliu.
Oti ni awọn ọlọpaa ri iṣana, eyi ti oun pẹlu awọn ikọ rẹ fẹẹ fi dana sun ọja naa, ada ati kumọ lọwọ awọn afurasi naa. O fi kun un pe awọn agbofinro ṣi n wa awọn afurasi to ku. Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni Saliu jẹwọ pe nitori pe adugbo naa lawọn n gbe ni awọn fi n da aṣọ boju.
Ṣa, Imohimi Edgal ti i ṣe Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko ti ni laipẹ ni oun yoo wọ wọn lọ si kootu, nibi ti oun yoo ti ba Saliu atawọn afurasi yooku ṣẹjọ.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.