Awọn ọlọpaa fẹẹ mu baba atiya ti wọn lu ọmọ wọn pa l’Akurẹ.

Spread the love
Testimony Babalọla nigba to ṣi wa laye

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ni awọn ti n wa gbogbo ọna lati fi panpẹ ọba gbe tọkọtaya kan ti wọn fẹsun kan pe wọn lu Testimony Tookẹ Babalọla, ọmọ bibi inu ara wọn pa l’Akurẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja.

Fẹmi Joseph to jẹ alukoro ileesẹ ọhun sọ lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii pegbogbo igbesẹ to yẹ lawọn n gbe lọwọ lati ri i daju pe ọwọ tẹ Ọgbẹni Felix Babalọla ati iyawo rẹ laipẹ rara, ki wọn le waa sọ tẹnu wọn lori ọrọ iku ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrin ọhun.

O ni ọpọ igba lawọn ti de ile ti wọn n gbe l’Akurẹ, ṣugbọn ti awọn ko ba wọn, ṣugbọn o ni awọn ko ni sinmi titi ti wọn yoo fi ri awọn afurasi mejeeji ọhun mu.

Gbogbo ẹyin rẹ ti wọn ti dapaa si tẹlẹ ree

Abilekọ Babalọla to jẹ iya ọmọdebinrin ọhun ni wọn lo gbe e digbadigba lọ sile-iwosan ijọba to wa l’Akurẹ ni irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, kawọn dokita to ba lẹnu iṣẹ l’ọjọ naa too fidi rẹ mul pe ọmọ to gbe wa ti ku.

Oriṣiiriii apa ti wọn ri lara oloogbe ọhun lasiko to fi wa nileewosan lo mu kawọn oṣiṣẹ ibẹ fura pe iku rẹ ko le jẹ oju lasan.

Obinrin yii ni wọn ri to gbe oku ọmọ rẹ pọn, to si sare jade nileewosan. Ko sẹni to mọ irin obinrin ọhun mọ titi dọjọ keji, ti Ẹni-Ọwọ Mathew Ologun to jẹ pasitọ ijọ Katliiki Mary Queen of Angels, to wa l’Akurẹ, nibi to ti n jọsin, too tu aṣiri oun atọkọ rẹ.

Alufaa ọhun ni bo tilẹ jẹ pe ọjọ pẹ ti tọkọtaya naa ti n fiya jẹ ọmọ yii, ọjọ keji,oṣu kẹfa, ọdun ta a wa yii lo ni oun ṣẹṣẹ n gbọ nipa rẹ.

Ninu iwadii to ṣe lo ni oun ti fidi rẹ mulẹ pe ọpọlọpọ oju ọgbẹ ati àpá to wa lara Testimony Babalọla ko ṣẹyin baba rẹFelix Babalọla, atawọn ara ijọ Kerubu, C & S, to ti n jọsin tẹlẹ, latari itusilẹ ti wọn ni awọn n ṣe fọmọ naa nitori ẹmi okunkun ti wọn lo n gbe inu rẹ.

O ni ọmọdebinrin yii ko ti i ju bii ọmọ oṣu mẹsan-an pere lọ nigba to ti n gbe lọdọ iya baba rẹ ni Ikarẹ Akoko, laipẹ yii lo ni ọkunrin naa lọ binu mu un kuro lori ẹsun pe iya oun ko ba oun kọ ọ lawọn ẹkọ ile to yẹ.

Iya Tesitimony sọ pe ọpọ egbo to wa lara ọmọ rẹ waye latari lilu lalubami nigba gbogbo lati ọwọ baba rẹ lori ẹsun pe ki i kunlẹ ki oun.

Ọwọ Testimony pẹlu apa

A gbọ pe Babalọla funra rẹ jẹwọ fun awọn eeyan kan to sun mọ ko too sa kuro l’Akurẹ pe asọtẹlẹ ti wọn sọ foun ninu ijọ Kerubu ti oun n lọ lo ṣokunfa awọn lilu atawọn ọgbẹ to wa lara rẹ.

Gẹgẹ bi iroyin ta a gbọ lati Ikarẹ Akoko, nibi ti tọkọtaya ọhun sa lọ, aarọ Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ naa lawọn ọlọpaa tọpasẹ wọn lọ sibi ti wọn sapamọ si, ti wọn si gbiyanju ati mu wọn lọ si teṣan wọn.

Eyi ni wọn n ṣe lọwọ tawọn oloye adugbo kan atawọn ọdọ diẹ fi jade si wọn,ti wọn si kọ jalẹ pe awọn agbofinro ko ni i mu wọn lọ.

Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye ni wọn ni meji ninu awọn ijoye ọhun bẹ awọn ọlọpaa to waa mu wọn pe ki wọn ṣi maa lọ na, wọn si ṣeleri lati funra wọn fa tọkọtaya naa le wọn lọwọ l’Akurẹ, lọwọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.