Awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori bi ina ṣe jo Iya Jimoh Ibrahim mọle l’Ekoo

Spread the love

Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa ina to jo Ọmọfẹmiwa Ibrahim, iya to bi ọkunrin olowo oniṣowo epo bẹntiroolu nni, Jimoh Ibrahim. Ṣe ni mama naa jona mọnu ile to n gbe laduugbo Victoria Gardeen City (VGC), niluu Eko.

Ni nnkan bii aago meji aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja ni ina ṣadeede ṣẹ yọ nile mama naa, ko si too di pe awọn oṣiṣẹ panapana de ibi iṣẹlẹ naa, mama yii ti dagbere faye. Wọn ti gbe oku rẹ pamọ si mọṣuari.

Lẹyin ọdun 2011 ti mama naa gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe ni Igbotako, nipinlẹ Ondo, lo dero ipinlẹ Eko, to si n gbe nitosi ile ọmọ rẹ ni VGC. Ilu Sapele, nipinlẹ Delta, ni wọn ti tu mama naa silẹ pada lẹyin ti awọn ẹbi rẹ san owo idoola.

Ilu Dubai ni Jimoh Ibrahim, ẹni to nileeṣẹ Energy Group, Nicon Insurance ati ileeṣẹ ọkọ ofuruufu Air Nigeria, n gbe bayii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Chike Oti, fidi iroyin naa mulẹ. O ni wọn ti gbe oku mama olowo naa pamọ si ọsibitu, awọn ọlọpaa si ti bẹrẹ iwadii lati mọ nnkan to fa ina to ṣẹ yọ yii.

 

 

 

 

Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti ni ki ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji kan, Amusa Rasaq, lọọ maa ṣere lọgba ẹwọn

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.