Awọn ọlọpaa beere lọwọ Fẹla pe ki lo n jẹ Kalakuta, ati idi to ṣe fi mọto silẹ, to jẹ kẹtẹkẹtẹ lo n gun kiri Eko

Spread the love

Ohun meji ni awọn ọlọpaa ti wọn wa sibi ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn Fẹla fẹẹ mọ. Iyẹn niwaju igbimọ Adajọ Kalu Anya to n gbọ ohun to ṣẹlẹ gan-an lọjọ ti awọn ọlọpaa dana sun ile Fẹla ni. Ojoojumọ ni igbimọ naa n jokoo lati igba ti wọn ti bẹrẹ iṣẹ, wọn o si fi ọjọ kan sinmi, wọn ni awọn fẹẹ mọ idi ti ija naa fi waye, ati ki lo de ti ija kekere bẹẹ di rogbodiyan, to si waa di ohun ti apa ẹnikẹni ko ka mọ. Awọn Adajọ Anya ni ijọba apapọ n duro de awọn, awọn ko si le fi akoko ṣofo, awọn fẹẹ yanju ọrọ naa kia, ki ijọba le mọ ohun ti yoo ṣe, ki gbogbo ariwo ti ọrọ naa mu dani le lọ silẹ pata, ki kaluku si maa ba iṣẹ rẹ lọ lai tun ni i si wahala kankan. Iyẹn lawọn ọlọpaa ṣe wa nibẹ, ti awọn ọmọ Fẹla ti wọn n ba a kọrin ati awọn ti wọn lu wa nibẹ, ti Fẹla ati awọn lọọya rẹ naa si jokoo lati mọ bo ṣe n lọ.

Nigba ti ọrọ naa fẹju daadaa, awọn ọlọpaa ni awọn fẹẹ mọ nnkan mẹta, awọn si fẹ ki adajọ ba awọn beere lọwọ rẹ, idi to fi ṣe wọn. Akọkọ ni pe ki lo de to koriira awọn ṣọja titi debii to ṣe odidi awo orin kan fun wọn, to si n pe wọn ni Zombie. Ẹẹkeji ni pe ki lo de to n pe ile rẹ ni Kalakuta, ko si pe e ni Kalakuta nikan, Orilẹ-ede Kalakuta lo n pe e: Kalakuta Republic. Ko si sọ idi to ṣe fi mọto silẹ to jẹ kẹtẹkẹtẹ lo n gun kiri. Awọn ọlọpaa sọ fun Adajọ Anya pe afi ti awọn ba mọ idi ọrọ naa, iyẹn ni yoo jẹ ki gbogbo wahala to wa nilẹ yii yanju o, ti ọkan onikaluku yoo si balẹ lẹyin ti awọn ba ti pari ọrọ naa tan. Wọn ni lọkan tawọn, awọn ko ni ija pẹlu rẹ, oun lo n ba awọn ọlọpaa ati ṣọja ati ijọba ja, ṣugbọn awọn mọ pe ohun to jẹ ki ija naa tubọ le ko ju awọn ohun ti awọn darukọ yẹn lọ: Ki lo n jẹ Kalakuta, ki si ni idi ti Fẹla fi n kọrin bu awọn ṣọja!

Adajọ Anya yiju pada, o si feesi Fẹla, o doju kọ ọ taara, o ni ọrọ loun naa kuku ti gbọ yii, ko ṣalaye idi to fi n pe ile rẹ ni Orilẹ-ede Kalakuta, nigba ti awọn mọ pe orilẹ-ede kan naa lo wa ni gbogbo agbegbe yii, orukọ ti orilẹ-ede naa si n jẹ ki i ṣe Kalakuta, Naijiria ni. Ati pe yoo tun ṣe alaye ohun to fa ija oun atawọn ṣọja, ati idi ti awọn ṣọja fi n ba a binu, ti oun naa si lọọ kọ odidi awo orin kan to fi n pe awọn ṣọja yii ni Zombie. O ni ọrọ lo ti gbọ yẹn, awọn ọlọpaa ti ni awọn fẹẹ mọ idi rẹ, ki awọn le mọ ohun ti awọn yoo ṣe. Gbogbo bi won ti n sọrọ naa ṣaa o, ẹrin ni Fẹla n rin. O ti wo oju awọn ọlọpaa, paapaa ọga wọn ti wọn n pe ni Abubakar Tsav bi iyẹn ṣe n sọrọ to n laagun, to si n ṣe bii ẹni pe bo ba tun ri ija, yoo ja a nibi to wa nni, bẹẹ lo si ti gbọ ohun gbogbo ti Adajọ Anya funra rẹ sọ. Ni oun naa ba tẹnu bọrọ.

Fẹla ni, lakọọkọ, oun dupẹ lọwọ Adajọ Anya ati awọn ọlọpaa paapaa, nitori ohun ti ko ba ye ni, a aa beere ni. O ni Kalakuta ti wọn n gbọ yẹn ki i ṣe orukọ ẹnikan, orukọ ti wọn n pe yara kan ninu awọn yara to wa lọgba ẹwọn ni Ikoyi ni. O ni ki i ṣe iyẹn nikan ni yara ti wọn fun ni orukọ nibẹ, yara kan tun wa ti wọn n pe ni Timbuktu, o ni itumọ iyẹn ni “Ọkọ aarọ kutukutu to gbera ti ko de ibi to n lọ!” O ni ẹni to ba gbọ iru orukọ bẹẹ yoo ti mọ pe awọn ti wọn ba ti mọbẹ, wọn ko fẹ ki wọn jade laaye ni, tabi ko jẹ ọjọ ti wọn yoo jade nibi ti wọn ti wọn mọ yẹn, ko sẹni to mọ, ẹnikan ko ni i le sọ. Ṣugbọn o ni ohun ti oun ri ni ti Kalakuta ni pe awọn ọlọgbọn, awọn onilaakaye ti ki i ṣe pe wọn ṣẹ ẹṣẹ kan to le, to jẹ ẹṣẹ bii ẹṣẹ oṣelu, tabi ẹni ti ijọba fẹẹ pa lẹnu mọ nitori ọgbọn ori rẹ ni wọn n ti mọbẹ.

Fẹla ni oun roye pe awọn ọlọgbọn pọnnbele lo wa nibẹ, koda, awọn ti ko yẹ ki wọn ti mọle tabi sọ sẹwọn lo pọ ninu wọn, nitori awọn ọlọgbọn to yẹ ki wọn wa laarin ilu, ki wọn maa fi ọgbọn ori wọn tun Naijiria ṣe ni. Ṣugbọn ijọba ti wọn mọbẹ, wọn ko tilẹ jẹ ki ọpọ eeyan mọ pe ibẹ ni wọn ti wọn mọ, wọn kan n fi akoko ati laakaye awọn eeyan bẹẹ ṣofo, aye ko si mọ ohun to n lọ. O ni oun paapaa ko kuku ni i mọ pe iru yara bẹẹ wa nibẹ, afi igba ti wọn waa ti oun naa mọ ọn, o ni nigba ti wọn ti oun mọbẹ loun ba awọn eeyan pade, ṣe ohun ti wọn si tori rẹ mu oun naa lọ sibẹ ni pe wọn ni oun n mugbo, ki i ṣe pe oun jale tabi oun paayan, tabi pe oun ko lọgbọn lori, ṣugbọn wọn ni oun n mugbo ni. O ni iru awọn ọlọgbọn bii toun loun ba nibẹ, ni awọn ti wọn ko ni ẹṣẹ kan pato ju pe ijọba koriira wọn lọ.

Fẹla ni oun ko fẹẹ gbagbe Kalakuta, oun ko si fẹẹ gbagbe awọn eeyan to wa nibẹ, iyẹn loun ṣe jade ti oun pe orukọ ile oun ni Kalakuta, ki i ṣe nitori lati maa ranti ibi ti wọn ti oun mọ yii nikan kọ o, ṣugbọn nitori lati maa ranti awọn eeyan ibẹ, ki ẹri ọkan le maa jẹ awọn ti wọn n ṣejọba. O ni oun pe ile oun ni Kalakuta Repbulic, ko le ni itumọ si ijọba orilẹ-ede awọn ọlọgbọn ti ijọba fẹẹ pa lẹnu mọ, itumọ orukọ ile oun niyẹn, oun ko si fi ba ẹnikẹni wi, oun n sọ ọ ki gbogbo aye le mọ bi oun ti n ronu si ni. Fẹla ni ohun to waa kan ijọba ninu pe oun sọ ile oun ni Kalakuta Republic ko ye oun, nigba to ṣe pe awọn ti wọn mu bii ọdaran ti wọn ti mọle nibẹ ni wọn sọ orukọ ara wọn bẹẹ, ki i ṣe ijọba lo n pe wọn bẹẹ, ewo waa ni tiwọn lati maa tori ẹ binu, ti wọn si n fikanra ọrọ ti ko kan wọn mọ oun.

Bo ti n sọ bẹẹ ni Adajọ Anya n kọwe, bo ba si jẹ ẹnikan ti kinni naa ko ti mọ lara ni, ko si ki ọwọ rẹ ma bo, iwe kikọ ọhun ti pọ ju, nitori ko ṣi oju soke bayii, afi igba ti Fẹla too pari ọrọ rẹ. Nigba ti Fẹla si sinmi ni Adajọ naa mi kanlẹ, ọrọ naa ye e ju bẹẹ lọ. Awọn eeyan ti wọn wa nibẹ paapaa patẹwọ ni, nitori ko too di ọjọ naa, ọrọ naa ko ye awọn paapaa to bẹẹ, ohun ti kaluku n gbọ ni Kalakuta, ko si ẹni to mọ idi ti ọkunrin naa fi pe orukọ ile rẹ ati adugbo rẹ bẹẹ, wọn kan ro pe orukọ kan lasan lati ilu oyinbo ni, afi nigba to ṣalaye, alaye naa si ya gbogbo awọn ti wọn wa nibẹ ti wọn gbọ ọ lẹnu. Bẹẹ lo pada jọ awọn ti wọn pada n royin ọrọ naa fun lọjọ keji loju, wọn ni aṣe idi ti ile ọkunrin olorin naa fi n jẹ orukọ nla yii ree. Awọn ti wọn tilẹ wa nibẹ n reti ohun ti Adajọ Anya yoo wi ni, ṣugbọn oun naa ko wi nnkan kan le e.

Kaka ko wi nnkan kan le e, ọrọ to sọ ni pe alaye eleyii ye gbogbo wa, eyi to ku ti a tun fẹẹ gbọ ni ti awọn ṣọja, ki lo wa laarin yin, nigba ti ẹ ko gba iyawo ara yin, abi ọrọ obinrin pa yin pọ ni! Ọrọ naa mu ẹrin jade leti awọn ti wọn gbọ ọ, Fẹla naa si fi iyẹn sọrọ pe oun ko gba iyawo ṣọja o, bi o ba jẹ ọrọ obinrin ni, oun gan-an loun le binu pe awọn ọmọ wọn, iyẹn awọn ṣọja keekeeke n waa ba awọn ọmọbinrin oun to n kọrin foun sun, nitori bi awọn ba ti ṣere tan ni wọn maa n gbe wọn lọ, tabi ki wọn ki wọn mọ kọna kan, oun yoo si ṣe bii ẹni pe oun ko ri wọn. O ni awọn onibaara ti awọn ọmọbinrin oun maa n ni ju lọrẹẹ lawọn ṣọja, wọn ko le ṣe ki wọn ma wa si ibi iṣere awọn, nitori yatọ si pe wọn fẹran orin oun gidi, wọn yoo tun wa sibẹ lati waa gbe ọmọ ni, awọn gan-an ni wọn n mu awọn ọmọ oun mọlẹ.

Fẹla ni ohun ti oun le sọ pe o fa ija oun ati awọn ṣọja ko ju nigba ti wọn ṣe ofin kan lọdun to kọja, iyẹn ọdun 1976, lọ. O ni nibẹrẹ ọdun naa ni wọn ṣe ofin ọhun, ofin ti wọn si ṣe ni pe ki awọn ṣọja maa ko koboko bo gbogbo onimọto loju titi, ki wọn maa na wọn ni koboko bi wọn ba ti ṣẹ si ofin irinna. O ni loootọ loun jade ti oun sọ pe iwa naa ko dara, nitori ilu awọn ẹranko nikan ni wọn ti maa n ko ṣọja jade, ti wọn yoo ni ki wọn maa na araalu. Bi araalu ba ṣẹ sofin kan, ọlọpaa ni yoo mu un wọọrọ, wọn yoo si mu un lọ si ibi ti wọn yoo ti ti i mọle, titi ti wọn yoo fi fiya ẹṣẹ to ba ṣẹ jẹ ẹ. Ṣugbọn ki ijọba kan waa sọ pe ki awọn ṣọja jade, ki wọn maa da awọn eeyan dọbalẹ loju titi, ki wọn si maa na wọn, iwa ti ko ba ilu awọn ọlaju mu ni, ko si yẹ ka gba iru rẹ laaye, nitori awọn ọmọ Naijiria ki i ṣe ẹranko.

O ni loootọ ni pe awọn ko ẹgbẹ awọn ọdọ kan jọ, ‘Nigerian Youths Liberation’, ẹgbẹ naa si kọwe lati fi ẹhonu wọn han si ijọba pe ko ma ṣe bẹẹ, ko ma ṣe ofin pe ki wọn maa na awọn onimọto ni popo. O ni Ọgagun Riki Tarfa ni wọn gbe iṣẹ a n naayan ni inakuna kiri titi yii fun, iyalẹnu lo si jẹ fawọn nigba ti oun naa jade, to ni ko si ki awọn ma na awọn onimọto loju popo, nitori alaigbọran lawọn ọmọ Naijiria, paapaa awọn onmimọto, ede kan ṣoṣo to si maa n ye wọn naa ni koboko, bi wọn ba ko koboko bo wọn lori wọn maa n pe. Fẹla ni bawo ni eeyan kan yoo ṣe sọ bẹẹ jade, ni ẹni to jẹ iṣẹ to n ṣe yii, awọn ọmọ Naijiria ni wọn n san owo oṣu rẹ, bawo ni yoo ṣe waa maa sọ pe ede kan ṣoṣo ti awọn ọmọ Naijiria yii gbọ ni koboko, ki awọn ṣọja maa ko koboko bo wọn kaakiri lo daa.

O ni ki oloju too ṣẹju, wọn ti bẹrẹ si i na awọn eeyan kiri titi loootọ, ifiyajẹni naa si pọ debii pe oun ko ri ara gba a si rara. Iyẹn lawọn ṣe kọ iwe si Tarfa, oun ati awọn ọmọ ẹgbẹ awọn, awọn si ṣalaye fun un pe iwa to n hu ko dara, ko ma sọ orilẹ-ede yii di tawọn ẹranko. Fẹla ni Tarfa gba iwe naa, o si da esi pada foun pe inu oun dun si i, o waa ni ki awọn wa sipade ni baraaki ki oun le ṣalaye awọn ọrọ naa foun daadaa. Fẹla ni oun mọ pe bi ọrọ ba ti da bẹẹ yẹn, ọrọ ṣọja ko ṣee tẹlẹ, awọn le debẹ taidebẹ bẹẹ ki wọn bẹrẹ si i kogi bo awọn ọmọ oun, ki wọn ni awọn ni wọn kọwe ti wọn n di ijọba Naijiria lọwọ, pe awọn tilẹ le debẹ ki wọn ma jẹ ki awọn ri Tarfa funra ẹ, ko jẹ awọn gbẹẹgbẹẹ ṣọja kan lawọn yoo ri ti wọn yoo maa jagbe mọ awọn, iyẹn loun ṣe kọwe pada si Tarfa, paapaa nigba to ti sọ pe oun fẹ koun Fẹla naa ba wọn wa.

Fẹla ni ninu iwe ti oun kọ si Tarfa, oun ṣalaye fun un pe oun ko fẹ wahala, oun ko si fẹ ki wọn maa pariwo orukọ oun pe Fẹla tun de o, pe to ba jẹ loootọ lo fẹẹ ba awọn ṣepade, ti inu rẹ dun lati ṣalaye ọrọ fawọn, ko jẹ ki awọn pade nibi ti ki i ti i ṣe baraaki, ti ki i si i ṣe ile oun Fẹla, nitori bi awọn ba wa si baraaki, ija le de nibẹ, bi awọn ba si wa si ọdọ oun naa, ija le de, ṣugbọn ki awọn lọ si ibi ti ilẹ ti tẹju, ti ki i ṣe adugbo ẹnikankan ninu awọn, awọn yoo le raaye sọ ohun ti awọn ba fẹẹ sọ. Fẹla ni Ọgagun Tarfa ko da esi pada foun, nigba ti ko si ti da esi pada bẹẹ, ki loun waa fẹẹ ṣe, iyẹn loun naa ṣe n woran. Ṣugbọn ni gbogbo ibi ti oun ba ti ri awọn ṣọja ti wọn ba n na awọn eeyan ni popo loun ti maa n kilọ fun wọn pe ki wọn ma ṣe bẹẹ mọ, ki wọn yee ko koboko bo awọn eeyan, nitori awọn araalu ki i ṣe ẹranko.

O ni ki Anya ma da awọn ọlọpaa loun o, awọn ti wọn sọ pe awọn ọmọ awọn n ba awọn ṣọja ati ọlọpaa fajangbọn loju popo, Fẹla ni ko si ohun to jọ ọ. O ni nitori ki wahala yii ma baa maa ṣẹlẹ laarin oun ati awọn ọlọpaa lo ṣe jẹ kẹtẹkẹtẹ loun maa n gun ni toun, oun ki i gun mọto, ko ma di pe gosiloo n mu oun, tabi pe ọlọpaa abi ṣọja kan yoo ni oun wa mọto lọna ti ko daa, ti yoo waa ni ki oun waa jẹ koboko. O ni oun mọ iwọn ara oun ni o, awọn onimọto ni ofin ti wọn ṣe mu, ko mu ẹni to ba n gun kẹtẹkẹtẹ, iyẹn lo ṣe jẹ kẹtẹkẹtẹ loun maa n gun lọ sibi yoowu ti oun ba fẹẹ lọ. O ni ṣe eeyan le tun gun kẹtẹkẹtẹ laarin ilu ko daran ni, jẹẹjẹ loun n gun kẹtẹkẹtẹ oun kiri, awọn ọlọpaa si tun n binu siyẹn naa. Awọn sọja naa ni awọn ọdaran lawọn ọmọ oun. Bẹẹ awọn ọlọpaa ko jẹwọ ni o, awọn ọmọ oun gan-an lo maa n ba wọn mu awọn ole adugbo, ko si ole kan ti i de adugbo awọn jale, Eewọ ni!

Fẹla ni loootọ loun ṣe awo orin oun jade ti wọn pe e ni Zombie, awọn ṣọja si n wa si ile-ijo oun ti awọn jọ n ṣere, ti wọn n jo si orin naa daadaa, wọn si mọ pe ki i ṣe awọn loun n forin oun ba wi. Ṣugbọn awọn ọga wọn ti wọn n ṣejọba ti wọn n wa ọna lati da wahala si oun lọrun ni wọn bẹrẹ si i yi orin naa pada lọdọ tiwọn, ti wọn si n sọ ohun ti ko ṣẹlẹ. O ni orin ti oun kọ yii, gbogbo Afrika loun ba wi, owe loun si fi pa. Owe ti oun pa naa ni pe awọn olori orilẹ-ede Afrika gbogbo ki i da ronu, nigbakigba ti awọn oyinbo ba ti halẹ mọ wọn, tabi ti wọn ba ti gbe eto radarada kan kalẹ, tabi ti wọn ba fi ọgbọn tan wọn lori ohun kan, awọn olori ijọba Afrika wọnyi ki i le da ronu ki wọn si kọ fun wọn pe awọn ko fẹ ohun ti wọn gbe wa yii, awọn ko ni i gba lae. O ni itumọ orin Zombie niyẹn, awọn ti wọn n ṣejọba Afrika loun fi ta ji.

Fẹla ni oun fẹ ki awọn olori ilẹ Afrika wọnyi ronu ni, ki wọn yee gba gbogbo ohun ti awọn oyinbo ba gbe wa, nitori niṣe ni wọn n pe eeyan dudu ni ọdẹ, ti wọn n pe wa ni ẹranko, iyẹn ni wọn ṣe n fẹ awọn ohun ti wọn n gbe waa ba wọn yẹn, wọn si ti mọ pe awọn olori wọn ko ni i le yi awọn lohun pada. Fẹla ni nijọ ti olori orilẹ-ede kan ni Afrika ba ti le tako awọn oyinbo yii, to si jẹ ki wọn mọ pe awọn ki i ṣe ẹru tabi ọmọ ọdọ wọn, lati ọjọ naa ni iṣoro gbogbo Afrika yoo ti dinku, ti awọn oyinbo ko ni i fi ilọkilọ kan lọ wọn mọ. O ni wọn kan n lo Afrika lati tun orilẹ-ede tiwọn ṣe lasan ni, bi wọn ba si lo wa tan, ti wọn ko owo Afrika lọ tan, wọn yoo tun maa bu wọn pe wọn ko laju. O ni kaka ki awọn olori Afrika yii si yipada, wọn yoo maa sa tẹle wọn lẹyin ṣoo-ṣoo ni, iyẹn lorin Zombie ṣe ba wọn mu.

Fẹla ni bi orin Zombie ti oun kọ fun gbogbo Afrika ṣe waa di eyi ti awọn ṣọja Naijiria sọ di tiwọn, ti wọn n tori ẹ ba oun ja, ti wọn sọ ọrọ naa di rannto, ti wọn ba ohun ini olowo iyebiye jẹ, ti wọn dana sun ile oun, ti wọn sọ iya oun lati ori oke ile bọ silẹ, alaye ti oun fẹẹ gbọ lẹnu wọn niyẹn o. Ọrọ naa ka Adajọ Anya laya, ko le wi nnkan kan. Awọn lọọya paapaa duro, awọn ọlọpaa ko le sọrọ, ohun ti wọn ro kọ ni wọn gbọ lẹnu Fẹla, ọrọ naa si sọ gbogbo wọn di ọbọ, wọn n wo suu! Ni Adajọ Anya ba dide, o ni nibi ti ọrọ de yii o, afi ki awọn de ile Fẹla ti wọn dana sun, ki awọn wo bi ibẹ ṣe ri, ki awọn wo ofo ati adanu ti wọn n royin yii, nigba naa ni awọn yoo too mọ ohun ti awọn yoo kọ fun ijọba.

N ni gbogo wọn ba ko riẹriẹ o. O di Kalakuta, ile Fẹla ti wọn dana sun.

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

(106)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.