Awọn ọlọpaa ṣi n wa baba ọmọ ọdun mẹrinla ti wọn lu pa l’Ọda

Spread the love

Awọn ọlọpaa ni awọn ṣi n wa  Ọgbẹni Adedayọ Ayọdele to jẹ baba ọmọ ọdun mẹrinla kan, Mathew Adedayọ, ẹni ti wọn lu pa niluu Ọda, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, nitori ẹgbẹrun mọkanlelogun Naira.

 

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, ni awọn ti fi panpẹ ọba gbe Abilekọ Adejọkẹ Adedayọ to jẹ iyawo baba oloogbe ati aburo rẹ, Idowu Adedayọ.

 

Ọkọ obinrin ọhun to n ṣiṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Delta ni iyawo rẹ pe sori aago, to si fẹjọ oloogbe sun un pe o ji ẹgbẹrun mọkanlelogun ninu ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira toun ko pamọ sile.

 

Eyi ni baba naa gbọ to fi pe aburo rẹ pe ko lọọ wadii ọrọ naa daadaa, ko si da sẹria to tọ fun ọmọkunrin ọhun to ba jẹ pe loootọ niru nnkan bẹẹ waye.

 

O ni ṣe ni Idowu ti ọmọ naa mọle, to si lu u nilukulu pẹlu koboko fun bii iṣẹju diẹ, bẹẹ niyawo baba rẹ naa tun la igi mọ ọn nibi to ti n gbiyanju lati gba oju ferese sa jade.

 

O ni lẹyin eyi ni iyawo baba rẹ ṣẹṣẹ lọọ wa waya ina kan jade, eyi to fi lu ọmọkunrin naa titi to fi daku mọ ọn lọwọ. Obinrin ọhun lo ni o fi ọmọ yii silẹ nibi to daku si, to si ba tirẹ lọ lai bikita boya o ku tabi o ye.

 

Awọn araadugbo to wa nitosi lo gbe Mathew lọ sileewosan kan, nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe o ti ku.

 

Fẹmi Joseph ni o di dandan ki awọn mu baba oloogbe ọhun nitori pe oun lo fun aburo rẹ laṣẹ lati ṣe iya fun oloogbe naa lọna aibofin-mu eyi to pada ja siku fun un.

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.