Awọn ọlọkada gba epo ọfẹ lorukọ Fayẹmi

Spread the love

Laaarọ ọjọ Aiku, Mọnde, ni okiki Ọmọwe Kayọde Fayẹmi ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ati Ọjọgbọn Kọlapọ Oluṣọla ti People’s Demcratic Party (PDP) gba ilu kan pẹlu bi awọn ọlọkada ṣe n gba epo ọfẹ lorukọ wọn niluu Ado-Ekiti.

Ileepo Mobil to wa ni Ajilosun ni APC ti pin epo lita marun-un marun-un fawọn ọlọkada, nibi ti ero ti pọ yanturu, ti wọn si n kan saara si Ọmọwe Fayẹmi.

Nigba ti oludije naa de ni nnkan bii aago mọkanla aarọ lariwo sọ, awọn ọlọkada naa si n sọ pe ko pada waa tun Ekiti ṣe.

Nibẹ lo ti rọ wọn lati ma gba gbogbo ẹsun ti PDP fi n kan APC Ekiti ati ijọba apapọ gbọ, o ni awọn eto ọmọniyan ti wọn yoo jẹgbadun toun ba wọle ko lẹgbẹ.

Ileepo NNPC to wa l’Ajilosun kan naa ni awọn ọlọkada ya bo, ti wọn si n gba lita marun-un marun-un lorukọ Ọjọgbọn Ẹlẹka. Ṣe lawọn eeyan naa n kan saara si oludije ọhun pe yoo tẹsiwaju ninu awọn eto ti Gomina Ayọdele Fayoṣe n ṣe lọwọ, bẹẹ ni wọn n fi asia PDP ati iwe ipolongo kọrin nibẹ.

(65)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.