Awọn ọlọdẹ to ji pata omo pasito ka l’Akure ti wa lodo olopaa

Spread the love

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti mu awọn afurasi meji kan, Samuel Linus ati Adekunle Ogundara, ki wọn le sọ ohun ti wọn mọ lori bi pata ọmọ pasitọ ṣọọṣi kan ṣe deedee di awati.

 

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, laaarọ kutukutu ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, ni ọkan ninu awọn ọmọ pasitọ ijọ Anglika Thomas Mimọ, to wa laduugbo Arakalẹ, Akurẹ, wa meji ninu awọn pata to sa sori okun ti wọn n sa aṣọ si ninu ọgba ṣọọṣi naa ti.

 

Awọn pata ọhun ni wọn ka lọ laarin oru ọjọ Aiku, Sannde, mọju ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja lasiko ti Linus ati Adekunle wa lẹnu iṣẹ ọdẹ ti wọn n ṣe lọgba ṣọọṣi naa.

 

Awọn to n gbe ninu ọgba ṣọọṣi ọhun sọ fun wa pe ketekete bayii lawọn n gbọ nigba ti aja nla ti wọn n sin n gbo kikan-kikan ni nnkan bii aago meji oru lọjọ naa.

 

Ohun to fi wọn lọkan balẹ ti wọn ko fi bikita lati jade ni awọn ọlọdẹ meji to wa lẹnu iṣẹ lasiko naa.

 

Gbogbo awọn to jẹ olugbe inu ọgba ileejọsin ọhun lo ya lẹnu nigba ti ilẹ ọjọ keji mọ ti pata meji ti dawati lori okun, ti ko si si eyikeyii ninu awọn ọlọdẹ mejeeji to n ṣọ wọn to le sọ ni pato bọrọ naa ṣe jẹ.

 

Idi niyi ti wọn fi fa Linus ati ọrẹ rẹ le awọn ọlọpaa lọwọ fun ifọrọwanilẹnuwo ati iwadii to jinlẹ lori ọrọ pata to sọnu.

 

Ninu alaye ti Linus ṣe fun wa nigba ta a n fọrọ wa a lẹnu wo, o ni oun nikan loun wa lẹnu iṣẹ loru ọjọ ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.

 

Adekunle to yẹ ki awọn jọ wa lẹnu iṣẹ ti kọkọ tọrọ aaye pe oun ko ni i le wa lalẹ ọjọ naa latari inu kan to ni o n yọ oun lẹnu.

 

O ni loootọ loun gbọ nigba ti aja n gbo loru, leyii to mu koun tu u silẹ, ti awọn si jọ n rin kaakiri gbogbo ayika ṣọọṣi naa, ṣugbọn ti awọn ko ri nnkan kan.

 

Aarọ ọjọ keji lo ni wọn ranṣẹ pe oun ati Adekunle, ti wọn si fa awọn le ọlọpaa lọwọ.

 

Ọrọ ti Adekunle sọ naa ko fi bẹẹ yatọ si ti ọrẹ rẹ. Ẹnikan to mọ bọrọ naa ṣe n lọ ṣalaye pe Adekunle ti figba kan jẹ ọkan ninu awọn ọmọ yahoo.

 

Laipẹ yii lo fẹnu ara rẹ kede pe oun ko fẹẹ ba wọn lọwọ ninu iṣẹ yahoo mọ, leyii to mu ko lọọ gba iṣẹ sikiọriti.

 

Ko ti i ju bii oṣu mẹta pere to bẹrẹ ni pata tun dawati nibi to ti n ṣiṣẹ.

 

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, juwe gbogbo ọrọ tawọn afurasi mejeeji sọ gẹgẹ bii awawi lasan. O ni ohun to ṣe awọn ọlọpaa ni kayeefi ninu iṣẹlẹ ọhun ni pe wọn le ji pata lọ ninu ọgba ti wọn gba odidi gende ọkunrin meji lati maa ṣọ.

 

O ni lẹyin tawọn ba pari iwadii lawọn afurasi naa yoo foju ba ile-ẹjọ.

 

 

 

(25)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.