Awọn oloṣelu n yẹyẹ awọn ọba wa, awọn ọba wa naa n yẹyẹ ara wọn

Spread the love

Nigba ti mo ri Oluwoo laarin awọn oloṣelu Ọṣun to n rẹrin-in, niṣe lo da bii ki n maa sunkun, nitori ọba naa ko ka iwe itan kankan, ko le fawọn ohun to ṣẹlẹ sẹyin ṣe ọgbọn. Bo ba mọ itan, to si wadii awọn ohun to ṣẹlẹ sẹyin ni, bo ba ri awọn oloṣelu ti wọn n lọ lọwọ ọtun, oun yoo maa gba osi lọ ni. Ọrọ ti mo si n sọ bọ nipa fifi ọba ṣe aṣaaju Yoruba, ati awọn ohun to ṣẹlẹ si wọn ti agbara ko fi si lọwọ wọn mọ ba eyi ti Oluwoo ṣẹṣẹ n ṣe yii lọ. Ọba to ba n ṣe oṣelu ko wulo fun ilu atawọn eeyan ẹ, nitori o n fi ọwọ ara ẹ fa iṣubu rẹ ni. Eyi ti ko si daa nibẹ ni pe bi ọba naa ba ṣubu tan, yoo tun gbe awọn eeyan ilu rẹ, ati ilu rẹ paapaa, ṣubu bi awọn yẹn ko ba tete mura sọrọ ara wọn. Ọtọ ni ki Ọlọrun funra rẹ fi eeyan ṣe olori ilu, ọtọ ni ka maa lakaka lati di olori ijọba ilu kan. Nibi yii ni ọba to ba mọ iwọn ara rẹ fi ju oloṣelu lọ.

Ọlọrun ni i fi ọba jẹ, to si n fi i ṣe olori awọn eeyan rẹ. Oloṣelu lo n lakaka lati di olori awọn eeyan rẹ. Bi Ọlọrun ba waa fi ọba kan jẹ, ti ọba naa ko mọ pe Ọlọrun lo n fi ni ṣe olori, to jọba tan, to n wa ipo bii ti olori ijọba, to n ba wọn ṣe oṣelu nitori ati maa ri igbakugba gba lọwọ awọn to n ṣejọba, nigbẹyin, awọn oloṣelu yoo fi ọba wọlẹ, tabi ki wọn yọ ọ loye, ifasẹyin yoo si ba ilu rẹ. Ọba to ba fẹran ara rẹ, to si fẹran ilu rẹ atawọn eeyan ibẹ, yoo jinna sawọn oloṣelu, nitori akobani lo pọ ninu wọn. Bi ẹ ba ti ri ọba kan to n yọ foroforo pẹlu awọn oloṣelu, to n lọọ ba wọn lọọfiisi, tawọn naa n lọọ ba a laafin, ọba bẹẹ yoo tẹ, yoo fi atẹ tẹdii, nitori bo ba ti n ba ẹgbẹ oṣelu kan ṣe ni yoo ti di ọta awọn aṣaaju ati ọmọ ẹgbẹ oṣelu keji, bẹẹ ilu kan naa ni gbogbo wọn wa. Nibi ti wahala ti n bẹrẹ niyẹn.

Ọba ti awọn oloṣelu ilẹ yii kọkọ yọ funra wọn ni Alaafin Ọyọ. Ni ọdun 1953 ni. Awọn ọba ilẹ Yoruba to ku n ba Awolọwọ ṣe, pupọ ninu wọn lo wa ninu ẹgbẹ Ọlọpẹ. Ṣugbọn Alaafin ko si ninu ẹgbẹ wọn, ko si ba awọn ọmọ ẹgbẹ yii ṣe. Bo ba jẹ pe o duro bẹẹ, ko ni i sija, ṣugbọn o n ba awọn ọmọ ẹgbẹ keji ṣe, ẹgbẹ NCNC, awọn Awolọwọ si ni ẹri eleyii lọwọ. Bo ba jẹ ni ilu to daa, ti ọrọ si ye ara wa ni, ko sohun to buru ninu iyẹn. Gẹgẹ bii eeyan, ẹgbẹ to ba wu u lo le ṣe. Ṣugbọn ọrọ oṣelu ilẹ yii ko ri bẹẹ rara, bi o ko ba ti ba ẹgbẹ wọn ṣe, ohun to le ko ọ yọ ni ki o ma ba ẹgbẹ mi-in ṣe, nitori lẹsẹkẹsẹ ni wọn yoo sọ ọ di ọta. Awọn ọmọ ẹgbẹ AG Ọyọ bẹrẹ si i sọ oriṣiiriṣii ọrọ fawọn Awolọwọ pe Alaafin n di awọn lọwọ nitori oun ni Baba Isalẹ awọn Ẹgbẹ PARAPỌ, ati pe awọn ọmọ NCNC lo wa ninu ẹgbẹ yii.

Awọn aṣaaju AG bẹrẹ si i gbọ ọrọ yii, ohun to si fa oju agan ti Bọde Thomas n gbe si Alaafin ree, nitori awọn iroyin ati ahesọ ọrọ to ti de eti wọn. Nigbẹyin, wọn fi ọrọ ti ko yẹ ko kan Alaafin so okun mọ ọn lọrun, iyẹn nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ AG ati NCNC ja ijaagboro laarin ara wọn. Wọn fi ọrọ yii kẹwọ, wọn si gbe ẹjọ rẹ siwaju awọn ọba ẹlẹgbẹ rẹ. Awọn ọba ti wọn gbe ẹjọ Alaafin siwaju wọn yii, awọn ọba yii naa n ṣe oṣelu o, ṣugbọn oṣelu ẹgbẹ Ọlọpẹ to wa nijọba ni wọn n ṣe. Nibo ni wọn fẹẹ da iru ẹjọ bẹẹ si ju ki wọn da Alaafin lẹbi lọ. Wọn da a lẹbi, wọn si le e niluu, ẹyin odi ti wọn le e lọ lọba naa si ku si. Bi ọrọ yii ti gbo Alaafin naa lo gbo ilu Ọyọ, nitori ọrọ ọhun ko tan nilẹ fun ọpọlọpọ ọdun, koda, nigba ti Adeyẹmi Kẹta to wa lori oye yii jẹ. Ohun ti ọba to ba n ṣoṣelu n da silẹ niyẹn.

Nigba ti awọn Awolọwọ yoo tilẹ ki ori awọn ọba yii sabẹ pata, wọn fun wọn ni ipo gẹgẹ bii oloṣelu, wọn fi wọn ṣe minisita, ki wọn le maa ri owo fun wọn. Awọn ọba kuku waa dojukọ oṣelu, wọn n ba wọn ṣe e loju mejeeji. Awọn ni wọn n kampeeni fẹgbẹ Ọlọpẹ, awọn ni wọn n ba araalu ti ko ba ṣe tẹgbẹ ja, ti wọn aa si mọ bi wọn ṣe maa sọrọ rẹ funjọba tabi Awolọwọ. Bẹẹ ọmọ ilu ti wọn jọba le lori ni o, ẹni to yẹ ko jẹ awọn ni wọn yoo daabo bo o bawọn araata kan ba fẹẹ fiya jẹ ẹ. Ṣugbọn nitori pe wọn ti n ṣe oṣelu, ti ẹni naa ko si si ninu ẹgbẹ tiwọn, wọn ko ni i kọ bi iya ba jẹ ẹ. Ko si wahala fawọn ọba yii titi ti ija fi de laarin Awolọwọ pẹlu Akintọla. Nigba ti ija de yii, gẹgẹ bi awọn oloṣelu ṣe n lọ sẹyin ẹni to wu wọn, bẹẹ lawọn ọba funra wọn n bọ sẹyin ẹni tawọn naa ba fẹ ninu Awolọwọ pẹlu Akintọla.

Ọọni Ifẹ funra rẹ to jẹ olori gbogbo awọn ọba yii nigba naa lo kọkọ fi ara gba nibẹ. Ṣe oun lo paṣẹ pe ki wọn yọ Akintọla nipo Prẹmia, nitori pe oun ni gomina-agba to le pa iru aṣẹ bẹẹ. Ṣugbọn Akintọla taku mọ ọn lọwọ pe ko sẹni to le yọ oun, ọrọ naa si di eyi ti wọn n gbe lọ si ile-ẹjọ. Nigba naa ni awọn Sardauna ati Balewa ti Akintọla sa lọọ ba ṣofin lojiji, wọn gba Western Region lọwọ ẹgbẹ Ọlọpẹ. Nigbẹyin, wọn da ijọba pada fun Akintọla, eyi si ja si pe Akintọla pada lagbara ju Ọọni lọ. Diẹ lo ku ki ijọba apapọ igba naa fi ọlọpaa mu Ọọni Adesọji Aderẹmi, wọn fẹẹ fi oun naa si itimọle inu ile (Home Arrest) ni Ibadan nibẹ, ti wọn o ni i jẹ ko jade, ṣugbọn olobo tete ta ọba naa, o si kuro n’Ibadan loru, o pada si aafin rẹ ni Ile-Ifẹ, ohun ti ko jẹ ki wọn ri odidi Ọọni fi si ahamọle niyẹn.

Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, Ọọni ko gbadun ori oye naa mọ lasiko ijọba awọn Akintọla, gbogbo ọna ni wọn n wa lati fi yẹyẹ ẹ, ti wọn yoo si maa fi i wọlẹ, nigba ti wọn mọ pe bii baba lo jẹ si Awolọwọ. Ọmọ Ile-Ifẹ ni Fani-Kayọde, ọmọ AG si ni. Nitori pe Ọọni ko fa a kalẹ lati dupo lo ṣe lọ sinu NCNC, ko too waa pada di ọrẹ Akintọla, ohun to si foju Ọọni ri lo n lọ lọhun-un nni. Bẹẹ ọmọ Ifẹ ni, ẹni ti ko yẹ ko woju Ọọni rara. Ohun ti oṣelu ati ọba to ba n ba wọn lọwọ si i n da silẹ niyẹn. Ninu awọn ti wọn sọ Akintọla di aya-koko-nnaki ninu ijọba rẹ, ti ko si le boju wẹyin mọ, Ọba Akran lati Badagry lẹni akọkọ. Oun ni wọn fi jẹ minista eto inawo, wọle-wọde Akintọla ati ọba naa si le gan-an. Igbẹyin ti awọn Akintọla ti ku tan lọba naa ṣẹwọn awọn ologun, nitori owo buruku ti wọn ri i pe o ji ko ni gbogbo igba to fi n tẹle Akintọla.

Ninu awọn ọba alagbara Yoruba, Ọba Ọlatẹru Ọlagbẹgi ti ilu Ọwọ, ọkan ni. Oun naa pada lẹyin Awolọwọ, o ba Akintọla lọ. Nigba tọrọ oṣelu pari, awọn araalu le e niluu, ijọba ologun si le e lori oye fun ọdun mẹẹẹdọgbọn. Wọn fi ọba mi-in jẹ l’Ọwọ, bi ko si jẹ ori to ba a ṣe e ti ọba naa waja lẹyin ti ọrọ naa ti rọlẹ daadaa ni, iyẹn lọdun 1993, ko si bi ọba naa iba ti tun gboorun ipo yii mọ, tori ọdun 1968 ni wọn ti le e. Tabi ohun ti Akintọla foju ọba alagbara ti wọn n pe ni Ọdẹmọ ilu Iṣara, iyẹn Ọba Akinsanya, ri leeyan yoo royin ni. Tabi ohun tawọn oloṣelu pada foju Awujalẹ kan naa to wa lori oye bayii ri. Ọba to ba ti n ṣe oṣelu ki i niyi loju awọn araalu ẹ, bo ba si niyi fungba diẹ, ẹtẹ ni yoo pada kangun fun un. Lasiko ti a wa yii, ọpọlọpọ awọn ọba Yoruba lo n ṣe oṣelu, bawo la ṣe fẹẹ ri aṣaaju gidi ninu wọn.

Eyi lo jọ pe awọn eeyan ṣe n darukọ Ọọni to wa lori oye bayii. Wọn ni Kabiyesi naa ko ba awọn oloṣelu ṣe rara. Ṣugbọn kan wa ninu eyi naa. Ṣugbọn wo tun niyẹn? A o ṣalaye ẹ lọsẹ to n bọ. Ẹ ṣa fi i sọkan pe bo ba gba wa ni asiko diẹ, ko buru, ṣugbọn dandan ni ki Yoruba ni aṣaaju, nitori nibi ti Naijiria n lọ yii, ajalu n bọ o. Mo sọ fun yin, mo tun tẹnu mọ ọn, ẹ si le kọ ọ silẹ nibi kan, ajalu n bọ ni orilẹ-ede yii, funra awọn aṣaaju wa ni yoo si fọwọ ara wọn fa a si wa lori. Awọn ti yoo ba a lọ yoo ba a lọ, Ọlọrun yoo si gba awọn ẹni tirẹ la. Ki Ọlọrun ka wa mọ awọn ti yoo la nijọ ti ajalu Naijiria yii ba de. Ṣugbọn pe ko ni i ṣẹlẹ yẹn, ẹ jẹ ka tutọ ẹ danu, o ti de tan! Ajalu ti ko si daa ni.

 

 

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.