Awọn oloṣelu fẹẹ ko tọọgi wọ Ekiti, ṣugbọn a n duro de wọn—Kọmiṣanna ọlọpaa

Spread the love

Iwadii awọn agbofinro ipinlẹ Ekiti lori ibo gomina to n bọ lọna ti fi han pe awọn oloṣelu kan n ṣegbaradi fawọn ọdọ kan lati da wahala silẹ, ṣugbọn ikilọ ti jade bayii pe ẹni tọwọ ba tẹ ko ni i bọ lọwọ ijiya ijọba.

 

Nibi eto kan tawọn ọlọpaa, ṣọja, Sifu Difẹnsi atawọn ileeṣẹ agbofinro mi-in peju si ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Ado-Ekiti ni kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti, Abdullahi Chafe, ti kede ọrọ ọhun.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ”A gbọ pe awọn oloṣelu kan ti ko awọn ọdọ kan jọ ti wọn n ṣegbaradi lọwọ lati da ipinlẹ yii ru lasiko ibo. A fẹẹ kede pe gbogbo awa ti eto aabo jẹ iṣẹ wa n duro de wọn o, kootu ni wọn si ti maa ba ara wọn nigbẹyin.

”Ibẹru ti wa bayii pe wahala maa ṣẹlẹ, ati pe ijọba apapọ maa lo awọn ẹṣọ alaabo lati jẹ ki ẹgbẹ wọn wọle, ṣugbọn mo fẹẹ sọ fun gbogbo eeyan pe Aarẹ Muhammadu Buhari ko lọwọ siru nnkan bẹẹ.

 

Bakan naa lo kilọ fawọn oloṣelu to wa nibẹ pe ki wọn tọwọ ọmọ wọn bọṣọ, o ni ko ni i si ojuṣaaju fun ẹnikẹni ninu wọn.

 

Lara awọn ọga eleto aabo to tun wa nibi ipade naa ni ọga ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ (DSS), Abilekọ Promise Iheanacho; ọga Sifu Difẹnsi, Ọgbẹni Donatus Ikemefuna; ati ọga ajọ ẹṣọ ojupopo, Ọgbẹni Ismail Kugu.

 

Awọn oloṣelu to peju sibẹ ni alaga ẹgbẹ Peoples Democratic Party (PDP) l’Ekiti, Amofin Gboyega Oguntuase; igbakeji akọwe ipolongo All Progressives Congress (APC) l’Ekiti, Ọgbẹni Gbenga Akinwumi; alaga ẹgbẹ Accord, Oloye Samuel Ọdẹọba; ati alaga awọn oniroyin l’Ekiti, Rotimi Ọjọmọyẹla.

 

(20)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.