Awọn oloṣelu da ayẹyẹ Iwo Day ru

Spread the love

Ṣe ni ọrọ di pẹ-n-tuka lọjọ Satide to kọja, nibi aṣekagba ayẹyẹ ‘Iwo Day 2018’ nigba ti awọn ori-ade atawọn alejo pataki ti wọn wa nibẹ binu dide lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADP ya wọ oju agbo naa.

 

Ṣaaju asiko ayẹyẹ yii ni Oluwo tilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, ti sọ pe oun ko ni i yọju sibi aṣekagba naa latari bo ṣe ni awọn igbimọ to ṣe kokaari eto ọhun kuna lati fi iwe ipe ranṣẹ si gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla.

 

Ṣugbọn lẹyin-ọ-rẹyin, wọn yanju ọrọ naa, Sẹnetọ Mudashiru Hussein si soju Gomina Oyetọla nibi eto ọhun, bẹẹ ni awọn ọba bii Ọlọfa ti ilu Ọfa, Ọba Muftau Gbadamọsi, Elegushi ti Ikateland, Ọba Saheed Ademọla, Akarigbo ti Rẹmọ, Ọba Adewale Ajayi atawọn ori-ade mi-in peju sibẹ.

 

Ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ni ayẹyẹ naa bẹrẹ lori papa iṣere ileewe DC School, Ararọmi, niluu Iwo, awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ati ti APC ti wa nijoko, bẹẹ ni Oluwo ko faaye gba ẹnikẹni lati lo anfaani ayẹyẹ naa fun ipolongo ibo.

 

Bo ṣe di bii aago meji kọja iṣẹju mẹwaa la gbọ pe oludije funpo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Democractic Party (ADP) lasiko idibo to kọja, Alhaji Moshood Adeoti de sibẹ pẹlu mọtọ bọọsi nla kan to jẹ ti oludije funpo sẹnetọ ninu ẹgbẹ naa.

 

Bọọsi nla yii ni wọn lo bẹrẹ si i ku eruku si awọn ọba atawọn alejo pataki ti wọn ti wa nijokoo lori, eleyii si bi Oluwoo pẹlu awọn ori-ade to wa nibẹ ninu, ni wọn ba dide pe awọn ko lee farada ohun to ṣẹlẹ naa.

 

Asiko yii naa la gbọ pe Alhaji Adeoti fẹẹ lọọ ki Oluwo lori ijokoo, ṣugbọn ṣe ni iyẹn fibinu sọrọ si i pe ki lo de to fi gbe mọto wọnu ibi ayẹyẹ naa pẹlu awọn alatilẹyin rẹ lai naani ọrọ ajọsọ to ti wa nilẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ sọ ibi ayẹyẹ naa di papa ipolongo ibo.

 

Bi ọrọ naa ṣe di iṣu ata yan-an-yan-an niyẹn, ti onikaluku bẹrẹ si i dide lẹyọkọọkan lai dagbere funra wọn, bẹẹ ni wọn doju ayẹyẹ naa ru.

 

Nigba to n sọrọ, akọwe ipolongo ibo fun Adeoti, Kayọde Agbaje, sọ pe awọn kan ti wiwa ti Adeoti pẹlu awọn ololufẹ rẹ wa sibi ayẹyẹ naa ko tẹ lọrun ni wọn binu kuro nibẹ.

 

Agbaje ni lai ka ti ohun to ṣẹlẹ naa si, eto ọhun lọ nirọwọ-rọsẹ, nitori gbogbo awọn ti Adeoti fiwe pe sibi eto yii ni wọn fi owo silẹ fun idagbasoke ilu Iwo. Lara wọn ni abẹnugan ile igbimọ aṣofin apapọ orilẹede yii tẹlẹ, Ọnọrebu Dimeji Bankọle ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.