Awọn ọdọ pa ọlọpaa l’Ekoo, wọn lawọn fi gbẹsan iku ẹlẹgbẹ awọn

Spread the love

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni wahala kan ṣẹlẹ ni adugbo Ifakọ Ijaiye to wa ni Ọgba, niluu Eko. Awọn ọdọ ti inu n bi lo ṣeku pa sajẹnti ọlọpaa kan, Esiabor Collins, wọn ni awọn fi gbẹsan iku ọkan ninu awọn ti wọn n pe ni Iṣan, to gbẹmii mi laaarọ ọjọ naa.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn ni ọdọ to ku naa ni awọn ọlọpaa kan ti kọkọ fiya jẹ ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin, ṣugbọn, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja ni ọmọkunrin naa pada jade laye.

Niṣe ni awọn eeyan yii kọlu awọn ọlọpaa teṣan ‘Area G Command’, to wa ni Ọgba, nibẹ si ni Sajẹnti Collins ti nọmba rẹ jẹ 260326, ti ku. Bọọsi nla kan ni wọn ni wọn gbe lọ si teṣan yii, ti wọn si ni wọn le ọlọpaa naa wọ kọrọ kan, nibi ti wọn ti ṣeku pa a.

Chike Oti, ti i ṣe alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, sọ pe eeyan marun-un ni ọwọ awọn ti tẹ lori iṣẹlẹ yii, ti awọn si ti gbe wọn lọ si ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran to wa ni Yaba, niluu Eko. O lo ṣee ṣe ki awọn fẹsun ipaniyan kan awọn ọdọ naa.

O ṣalaye pe iwadii ti awọn ti ṣe fi han pe awọn eeyan yii ṣa ara wọn jọ, wọn si lọ si teṣan ‘Area G’, to wa ni Ọgba, ohun ti wọn si fẹẹ ṣe ni pe ki wọn dana sun agọ ọlọpaa naa, ṣugbọn agbara wọn ko gbe e. O sọ pe ọga ọlọpaa ti wọn ba lẹnu iṣẹ fi wọn lọkan balẹ pe oun yoo ri si wahala naa, oun yoo si ri i pe awọn fiya jẹ ẹni to ba jẹbi, ṣugbọn awọn eeyan yii ko dahun, afigba ti wọn pa ọlọpaa yii. O fi kun un pe bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa naa lagbara lati fi ibọn wọn gbeja ara wọn, ṣugbọn wọn ko ṣe bẹẹ, ai ṣe bẹẹ si ni wọn fi ṣeku pa Sajẹnti Collins.

Oti waa rọ awọn obi lati kilọ fawọn ọmọ wọn ki wọn yee da aṣẹ pa lọwọ ara wọn, nitori irufẹ igbesẹ bẹẹ le fa wahala lawujọ.

(57)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.