Awọn ọdọ jo ile eegun to gun Fẹmi pa l’Akurẹ

Spread the love

Niluu Akurẹ ni awọn ọdọ agbegbe Gaga, Oke Aro, ti dana sun ile awọn eleegun ti wọn fẹsun kan pe wọn gun ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Fẹmi Makanjuọla, lọbẹ pa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Fẹmi ni awọn eegun kan ṣeku pa laduugbo Ọlọmọyẹyẹ, Oke Aro, niluu Akurẹ, ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, lasiko to fẹẹ ra nnkan to maa fi se ẹwa to gbe kana.

A gbọ pe awọn eleegun yi pade ọmọkunrin naa loju ọna, wọn si beere owo ọdun ti wọn n ṣe lọwọ rẹ. Kikọ ti oloogbe naa kọ lati fun wọn lowo ti wọn n beere fun lo da ariyanjiyan silẹ laarin wọn, nibi ti wọn si ti n fa ọrọ yii ni wọn ti gun ọmọkunrin naa lọbẹ pa.

Olori awọn eleegun ọhun Oluwagbamigbe Olowokere, lọwọ awọn ọlọpaa kọkọ tẹ, ki wọn too gbe Baba ẹni ọdun marundinlọgọrin kan, Alagba Adaramọla Ajulọkọ, ẹni ti i ṣe baba ọkan ninu awọn afurasi to ṣeku pa Fẹmi.

Olowokere to jẹ olori awọn eleegun ọhun ṣalaye pe ọdọọdun ni awọn maa n gbe eegun lasiko ti wọn ba ti n ṣọdun wọn.

Oun pẹlu awọn eegun meji mi-in, iyẹn Deji Dada ati Sunday Adaramọla, lo ni awọn jọ gbe eegun jade lọjọ iṣẹlẹ ọhun, ti awọn si n jo kaakiri ilu, titi tawọn fi pada si igbalẹ, nibi tawọn ti bọ ẹku wọn silẹ.

O ni afigba ti ọlọpaa waa ka oun mọle lalẹ ọjọ naa, ti wọn si fẹsun kan oun pe oun atawọn eegun meji mi-in paayan. Iyalẹnu lo ni o jẹ fun oun, ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ loun ti mọ pe Deji ati Sunday ti pada lọọ gbe ẹku ti wọn ti kọkọ bọ silẹ wọ, ti wọn si lọọ fi ṣiṣẹ laabi.

Baba Sunday, iyẹn Alagba Adaramọla, sọ pe ki wọn ṣaanu oun, nitori pe oun ko le fi arugbo ara ṣẹwọn nitori ọmọ. Baba yii sọ pe oun ki i ṣe eleegun, bẹẹ loun ko wa lati inu idile eleegun, o ni oun gbagbọ pe Sunday ọmo oun ti wọn fẹsun kan pe o wa lara awọn afurasi to pa Fẹmi ki i ba wọn gbe eegun, bo tilẹ jẹ pe loootọ lo maa n tẹle wọn.

Baba yii ṣalaye pe oun ti ba awọn ọlọpaa sọrọ, oun si ti ṣeleri fun wọn pe oun aa wa ọna ti oun yoo fi tan ọmọ oun to ti sa lọ naa pada wale.

Fẹmi ti wọn ṣeku pa yii ni wọn pe ni akẹkọọ-jade to ṣẹṣẹ ri iṣẹ si ileeṣẹ simenti Dangote, to wa niluu Benin. Ana, ọjọ Aje, Mọnde, lo yẹ ko bẹrẹ iṣẹ ọhun, ṣugbọn ti wọn da ẹmi rẹ legbodo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, ti sọ pe iwadii ti awọn ṣe fidi ẹ mulẹ pe Olowokere to jẹ olori awọn eleegun ọhun mọ nipa iku Fẹmi, afurasi tọwọ tẹ naa ati awọn ẹmẹwa rẹ meji ti awọn ọlọpaa ṣi n wa lo sọ pe wọn jọ gbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi ọhun.

Awọn ọlọpaa sọ pe awọn ko ni i sinmi titi tọwọ awọn yoo fi tẹ awọn afurasi meji to ti sa lọ yii mu, bẹẹ lo ni awọn ko ni i pẹẹ gbe Olowokere lọ sile-ẹjọ, nibi ti yoo ti kawọ-pọnyin rojọ niwaju adajọ.

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.