Awọn ọdọ Ekiti binu sijọba apapọ atawọn ileeṣẹ South Afrika

Spread the love

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Lopin ọsẹ to kọja lawọn ọdọ kan labẹ ẹgbẹ akẹkọọ ilẹ yii, National Association  of Nigerians (NANS) ati National Coalition for Yoruba Youth and Students, ṣewọde alaafia kaakiri ilu Ado-Ekiti to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ekiti.

Eyi jẹyọ lẹyin iroyin to gba ilu nipa bi wọn ṣe ṣeku pa awọn ọmọ Naijiria atawọn ajoji mi-in nilẹ South Afrika, ti wọn si tun ba dukia wọn jẹ, eyi to ti da awuyewuye silẹ kaakiri agbaye.

Iwọde awọn ọdọ ọhun to da sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ silẹ fun bii wakati kan ni wọn ṣe lawọn oju popo Ijigbo ati Baṣiri, niluu Ado-Ekiti.

Nigba to n sọrọ lori idi tawọn ọdọ naa fi tu jade, Ojo Raymond to jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ NANS sọ pe ki ilẹ South Afrika ṣọ ara wọn lori rogbodiyan ti wọn n da silẹ nitori apa wọn ko ni i ka a tawọn ọdọ Naijiria ba yari.

O ṣalaye pe ko yẹ kawọn ọmọ ilẹ yii maa ba awọn ileeṣẹ ilẹ South Afrika bii MTN, DSTV, Stanbic IBTC atawọn mi-in dowo-pọ, ki wọn wa awọn ileeṣẹ mi-in, kawọn eeyan orilẹ-ede naa le mọ pe ọrọ ọhun ki i ṣe ere rara.

O ni South Afrika ko le maa pa awọn ọmọ Naijiria, ki wọn tun maa jere nibi, nitori ilẹ Naijiria lo n gbe awọn ileeṣẹ wọn larugẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, aarẹ ẹgbẹ  National Coalition of Yoruba Youth and Students,  Sunday Ashefon, pe fun itusilẹ awọn ọdọ tileeṣẹ ọlọpaa mu lasiko iwọde ti wọn ṣe nipinlẹ Eko.

O sọ ọ di mimọ pe awọn ọdọ Naijiria ko faramọ iru igbesẹ bẹẹ nitori awọn ọlọpaa South Afrika ko ṣe nnkan kan fawọn to n pa ọmọ Naijiria, eyi to fi han pe wọn lọwọ si i.

Awọn oluwọde naa waa fun ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari lọjọ meje pere lati wa ojutuu sọrọ naa, bẹẹ ni wọn ni awọn ọdọ yoo jọ ijọba loju ti nnkan ko ba yipada.

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.