‘Awọn ọbayejẹ fẹẹ doju ileeṣẹ ọlọpaa kọ ijọba’

Spread the love

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, ti pe akiyesi awọn araalu si aworan ọlọpaa kan to wa kaakiri ori ẹrọ ayelujara, nibi ti ọlọpaa naa ti gbe akọle kan lọwọ, to ti n sọ pe ki i ṣe ojuṣe awọn ọlọpaa lati koju ikọ Boko Haram, Edgal ni irọ gbuu ni aworan naa.

Ninu atẹjade kan ti Edgal fi sita lati ọwọ Alukoro awọn ọlọpaa, Chike Oti, lọsẹ to kọja, lo ti ṣalaye pe  awọn eeyan lo pe akiyesi oun si aworan naa, nibi ti ọlọpaa kan ti gbe akọle ‘ki i ṣe ojuṣe wa lati koju Boko Haram, wọn ko kọ wa lọna ti a maa gba’, lọwọ, oun si mọ daju pe iṣẹ ọwọ awọn ọbayejẹ to fẹẹ doju awọn ọlọpaa kọ ijọba ni.

Edgal ni loootọ, aworan naa jẹ ti ọlọpaa to n ṣiṣẹ nipinlẹ Eko, iyẹn CSP Yusuf Ajape, ṣugbọn, ọjọ kẹrin, oṣu kọkanla, ọdun 2017,  ni Ajape ti ya fọto naa lasiko ti awọn n ṣe ipolongo gbigbogun ti iwa ibajẹ laarin awọn ọlọpaa, ni olu-ileeṣẹ naa to wa ni Ikẹja.

Ṣa, Oti ni awọn ti paṣẹ fun awọn ẹka imọ kọmputa lati ṣawari ẹni to ṣe adamọdi fọto naa, ki awọn si jẹ ki o koju ofin.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.