Awọn ọba ati awọn onikẹkẹ Marwa ṣatilẹyin fun gomina Ahmed lati dupo sẹnẹtọ ni Guusu Kwara

Spread the love

Awọn ọba alaye ati awọn eeyan agbegbe Guusu Kwara, ti fontẹ lu Gomina ipinlẹ naa, Abdulfatah Ahmed, lati dije dupo sẹnetọ.Bakan naa ni awọn ẹgbẹ onikẹkẹ Marwa naa ni awọn nifẹẹ si ki ọkunrin to n mura lati kuro ni ipo gomina naa tun dije fun ipo sẹnetọ yii.Olusin ti Isanlu-Isin, Ọba Solomon Olugbenga Oloyede, ẹni to jẹ alaga fun awọn ọba alaye sọ pe awọn ti fontẹ lu Ahmed, o ni ọkunrin naa kunju oṣuwọn. Ati pe, lasiko to fi jẹ gomina nipinlẹ Kwara, o ṣe awọn iṣẹ manigbagbe si ẹkun idibo awọn, idi eyi si ni awọn fi n fifẹ han si i pe ko dije naa. Ọba Oloyede waa dupẹ lọwọ gomina yii fun agbega to ṣe fun ipo Olusin ti Isanlu-Isin ati awọn iṣẹ pataki mi-in to ṣe si ẹkun naa.
Bakan naa ni Olosi tilu Osi, nijọba ibilẹ Ekiti, Ọba Adbulkareem Adesofẹgbẹ, ati Alọfa tilu Ilọfa, Ọba Samuel Niyi Dada, nijọba ibilẹ Oke-Ẹrọ, naa fi atilẹyin wọn han si Gomina Ahmed.
Wọn ni aṣeyọri rẹ yoo fun un lanfaani lati jawe olu-bori ninu idibo abẹle, bẹẹ ni yoo si tun jawe olubori  nibi eto idibo ọdun to n bọ.
Ahmed dupẹ lọwọ awọn ọba naa fun atilẹyin wọn, o si rọ awọn araalu lati ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu PDP, ki idagbasoke baa le ba eto ọrọ-aje orilẹ-ede yii.

(16)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.