Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Radio Kwara fẹdun ọkan wọn han nitori aisi ohun-eelo to dara

Spread the love

Gbogbo awọn to ba gba agbegbe ti ileeṣẹ Radio Kwara wa lagbegbe GRA, niluu Ilọrin, l’Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ to kọja yii lo maa mọ pe nnkan n ṣẹlẹ nibẹ. Niṣe ni wọn ti ẹnu ọna  abawọle ileeṣẹ naa pa, pẹlu bi awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọhun ṣe n fẹhonu han si ipo ti ileeṣẹ naa wa, ati awọn ohun-eelo ti ijọba ko pese fun iṣẹ wọn.

ALAROYE gbọ pe lara ohun to n dun awọn oṣiṣẹ naa lọkan ni bi wọn ṣe ni ijọba n gbero lati fagile ikanni igbohun-safẹfẹ AM.

Wọn ni ijọba ko awọn oṣiṣẹ lati ibi ti ileeṣẹ Radio Kwara wa bayii, ni Police Road, lọ si ibudo ti wọn ti n gbohunsafẹfẹ to wa ni Budo-Ẹfọ. Wọn ni ijamba nla ni ohun to n jade lati ara ẹrọ-alatagba to wa ni Budo-Ẹfọ n ṣẹ si agọ ara awọn to n ṣiṣẹ nibẹ.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ohun to n jade lara ẹrọ alatagba naa lojoojumọ maa n ṣe akoba fun atọ awọn ọkunrin to n ṣiṣẹ nibẹ, ti ko si ni i jẹ ko le di ọmọ.

Awọn oṣiṣẹ naa sọ pe ijọba gbọdọ yọ Fẹmi Akorede to n ṣakoso ileeṣẹ naa. Wọn ni irọ ati ẹtan patapata ni Akorede  sọ ninu ọrọ to sọ lori rẹdio aladaani kan laarọ Ọjọbọ Tọside,ọsẹ to kọja naa.

Wọn ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ilẹ ti waa wọn ilẹ ileeṣẹ Radio Kwara wo nirọlẹ Ọjọbọ, Tọside, eyi to fi han pe loootọ nijọba n gbero lati gbe ileeṣẹ naa ta.

Ṣa, ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣeleri pe laarin ọsẹ yii lawọn oṣiṣẹ Radio Kwara atawọn ti ileeṣẹ iwe-iroyin Herald yoo gba owo-oṣu ti ijọba jẹ wọn.

Dokita Muideen Akorede, to jẹ oluranlọwọ pataki gomina lẹka iroyin, sọ pe ijọba ti gbe miliọnu marun-un Naira kalẹ.

Akorede nigba to n sọrọ lori ifẹhonu han ti awọn oṣiṣẹ Radio Kwara ṣe, so pe oun ti n ba awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa sọrọ lori bi iṣẹ yoo ṣe maa lọ deede nileeṣẹ naa. Ṣugbọn aisi owo lo n mu ifasẹyin ba a, nitori pe owo to n wọle lati apo ijọba apapọ ko to nnkan mọ.

O ni ahesọ lasan lohun ti awọn kan n sọ pe ijọba fẹẹ gbe ileeṣẹ naa ta, o ni ko sohun to jọ bẹẹ rara. Akorede sọ pe ijọba ko ni i lero lati gbe awọn ileeṣẹ iroyin rẹ ta, nitori pe o ni igbesẹ ti ajọ NBC, ati ile igbimọ aṣofin gbọdọ mọ si ti ijọba ba fẹẹ ṣe bẹẹ.

O ni nitori ẹrọ alatagba to bajẹ nileeṣẹ Radio Kwara, lo mu ki ijọba ko awọn oṣiṣẹ lọ si ibudo igbohun-safẹfẹ to wa ni Budo-Ẹfọ.

Caption: Awọn oṣiṣẹ Radio Kwara to n fẹhonu han

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.