Awọn oṣiṣẹ ijọba tọwọ tẹ lori ẹsun ole jija yoo foju ba ile-ẹjọ

Spread the love

Lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ba pari iwadii ti wọn n ṣe lọwọ ni wọn sọ pe awọn oṣiṣẹ ijọba tọwọ tẹ lori ẹsun ole jija yoo foju bale-ẹjọ.

 

Alukoro awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Fẹmi Joseph, fidi ẹ mulẹ fun wa pe laarin ọsẹ to kọja yii ni ọwọ tẹ Abilekọ  Abiọdun Oluwatoyin, Ojo Ayọdeji, Ọmọyajowo David, Solomon Isaac, Tuki Fẹmi ati Ayede John Orimisan ti marun-un ninu wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo, nigba ti ẹni kan to ku jẹ agbodegba ti wọn n lo lati ṣiṣẹ ibi wọn.

 

Ayederu risiiti lawọn afurasi ọhun ti wọn n ṣiṣẹ nileeṣẹ ọtọọtọ to jẹ ti ijọba maa n ja fawọn agbaṣẹṣẹ to n ṣiṣẹ pẹlu ijọba.

 

Bakan naa lo ni wọn tun n lo ọkan ninu wọn lati ṣe ayederu iwe ọkọ fawọn araalu, asunwọn banki rẹ ni wọn si n tọju owo nla ti wọn ba pa si.

 

A fidi ẹ mulẹ pe, o pẹ diẹ ti wọn ti n ṣọ awọn oṣiṣẹ naa lọwọ lẹsẹ ko, too di pe ọwọ pada tẹ wọn laarin ọsẹ to kọja yii.

 

Wọn ti figba kan mu Abilekọ Toyin to jẹ obinrin kan to wa laarin wọn lori ẹsun yii kan naa, ṣugbọn wọn tun fi i silẹ lati maa ba iṣẹ rẹ lọ lẹyin to ti lo bii ọjọ diẹ ninu ahamọ.

 

Odidi ọdun mejilelogun ni wọn lo fi wa lọfiisi kan ṣoṣo, leyii to mu ko ṣee ṣe ko ni awọn ọga to n ṣiṣẹ fun.

 

Nigba ta a n fọrọ wa wọn lẹnu wo, meji ninu wọn, Toyin ati Ọmọyajowo, sẹ kanlẹ pe awọn ko mọ ohunkohun lori ẹsun ti wọn fi kan awọn. Wọn ni ko si igba kankan tawọn dari owo to yẹ ko lọ si apo ijọba sinu apo awọn, nitori pe iwe ati risiiti ijọba lawọn n fun awọn eeyan.

 

Ṣugbọn Orimisan ti wọn lo jẹ agbodegba fun wọn jẹwọ pe loootọ lawọn afurasi marun-un yooku gba oun lati maa ṣiṣẹ fun wọn, fifun awọn eeyan ni ayederu risiiti, iwe irinna ọkọ wa lara iṣẹ ti wọn gba oun fun, eyi to si n ṣe titi tọwọ fi tẹ wọn.

 

Joseph ni bawọn ba ti pari iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi yii ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.