Awọn oṣiṣẹ fẹsun kan Fayoṣe pe o ra mọto miliọnu mẹrinlelaaadọrin

Spread the love

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, Nigeria Labour Congress (NLC), ati Trade Union Congress (TUC), ti fẹsun kan Gomina Ayọdele Fayoṣe tipinlẹ Ekiti pe o ra mọto miliọnu mẹrinlelaaadọrin kan, bẹẹ lo fẹẹ san miliọnu mẹtalelogoji fun ara rẹ ati igbakeji rẹ ti wọn ba n lọ.

Ninu atẹjade kan ti Ọmọọba Ade Adesanmi to jẹ alaga NLC ati ojugba rẹ lati TUC, Ọgbẹni Ọdunayọ Adesoye, gbe jade ni wọn ti juwe iwa naa bii eyi to buru gidi.

Wọn ṣalaye pe o ya awọn lẹnu bi gomina ti ko sanwo oṣu ṣe le ronu mọto nla ati owo ajẹmọnu bẹẹ, ṣugbọn wọn ni nnkan ko ni i rọgbọ ti awọn igbesẹ mejeeji ba wa si imuṣẹ.

Bakan naa ni Adesanmi bẹnu atẹ lu iroyin to n lọ nigboro pe Fayoṣe fẹẹ ta awọn nnkan ini ijọba, o ni iwa ibajẹ gbaa ni, nitori ẹnikan ko le deede ta awọn nnkan to ti wa tipẹ laarin ọsẹ diẹ to ku fun un lati lo.

Awọn olori oṣiṣẹ naa waa ke sijọba lati ma dan igbesẹ naa wo rara, nitori yoo ko Ekiti sinu wahala nla.

Kọmiṣanna feto iroyin l’Ekiti, Lanre Ogunṣuyi, kọ lati fesi si ọrọ yii nigba ta a kan si i.

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.