Awọn mẹta dero kootu, ewurẹ ni wọn ji gbe n’Ikẹrẹ-Ekiti

Spread the love

Afurasi ọkunrin meji ati obinrin kan ti ha, wọn si ti gbe wọn lọ si kootu Majisreeti Ado-Ekiti bayii, lori ẹsun pe wọn ji ewure ati agbo gbe niluu Ikẹrẹ-Ekiti.

 

Akinfọlarin Ọkọdunrin (ẹni ọdun marundinlogoji), ati Samba Akanmu (ẹni ọdun mẹrindinlọgọta), ni wọn mu pẹlu obinrin kan, Ademọla Adejọkẹ, (ẹni ọdun mẹtalelogun), fun ẹsun ole jija ati gbigba ẹru ole.

 

Gẹgẹ bi alaye ti Inspẹkitọ Oriyọmi Akinwale ṣe fun ile-ẹjọ, ni nnkan bii aago marun-un idaji ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kin-in-ni to kọja yii lawọn eeyan naa huwa ọhun pẹlu bi wọn ṣe ji ewurẹ mẹrin ati agbo kan towo wọn to ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un (100,000) Naira.

 

Bakan naa lo ni Ajọkẹ ati Akanmu gbiyanju lati gba awọn ewurẹ kan lọwọ Akinfọlarin, ẹni ti ẹri wa pe o lọọ ji wọn ni.

 

Ẹsun ole jija ati gbigba ẹru ole yii lo tako abala irinwo-din-mẹwaa (390), ati ẹẹdẹgbẹta-le-mọkandinlogun (519), iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ekiti ti wọn ṣakọsilẹ rẹ lọdun 2012. Oriyọmi waa rọ kootu naa lati sun ẹjọ siwaju fun agbeyẹwo iwe ẹsun naa ati lati ko awọn ẹlẹrii jọ.

 

Awọn afurasi ọhun ni awọn ko jẹbi nigba ti kootu beere ọrọ lọwọ wọn, bẹẹ ni Amofin Toyin Oluwọle bẹbẹ fun beeli wọn pẹlu ileri pe wọn ko ni i sa lọ.

 

Majisreeti Modupẹ Afẹnifọrọ gba beeli awọn olujẹjọ pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta (50,000) Naira ati oniduuro meji niye kan naa.

 

Igbẹjọ di ọjọ kejilelogun, oṣu yii.

 

 

 

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.