Awọn mẹrin to lu akẹẹkọ KWASU ti wa lahaamọ

Spread the love

Ahaamọ ọgba-ẹwọn ni adajọ ile-ẹjọ ibilẹ to wa ni Adewọle, Adajọ Abdulganiyu Abdulrasaq, paṣẹ pe ki awọn olujẹjọ mẹrin kan, Gabriel Adepọju, Bamidele Ọlayinka, Makinde Fẹranmi ati Ayọmide wa, tabi ki wọn gba oniduuro wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta naira ati oniduuro meji fun ẹni kọọkan niye kan naa. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn lu akẹẹkọ Fasiti ipinlẹ Kwara, (KWASU), Abdullateef Ọladimeji, wọn si tun da apa si i lara.
Gẹgẹ bi Ọgbẹni Inyang to jẹ agbẹjọro fun ijọba ṣe sọ, o ni ọjọ kejidinlogun, oṣu keje, ọdun 2018, ni Abdullateef Ọladimeji to jẹ akẹẹkọ KWASU to wa ni Malete, fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti pe awọn olujẹjọ naa fẹsun kan oun pe oun ji foonu ọkan lara wọn, ti wọn si lu oun titi ti wọn fi da apa si oun lara.
Ọladimeji sọ pe gbogbo bi oun ṣe n sọ fun wọn pe oun ko mu foonu kankan, ni awọn olujẹjọ naa ko gba, ti wọn ko si dawọ lilu naa duro.
Awọn olujẹjọ naa sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun tile-ẹjọ fi kan awọn. Wọn ni loootọ lọrọ ṣẹlẹ laarin awọn, ti awọn si na Ọladimeji, ṣugbọn ki i ṣe pe awọn mọ-ọn-mọ ṣe bẹẹ. Ọkan ninu wọn sọ pe iru bata to wa lẹsẹ Ọladimeji lawọn ri lẹnu ọna yara ti foonu naa wa lasiko to sọnu, eyi lo fa a ti awọn fi fura si i.
Ọgbẹni Inyang ni ki ile-ẹjọ sun ẹjọ naa siwaju, ki ileeṣẹ
ọlọpaa le pari iwadii wọn to n lọ lọwọ. O tako gbigba oniduuro awọn olujẹjọ naa pẹlu bo ṣe ni ki wọn lọọ fi wọn sahaamọ ọgba-ẹwọn.
Adajọ Abdulganiyu faaye beeli awọn olujẹjọ naa silẹ, ṣugbọn ọkan ninu wọn lo ri eeyan ṣe oniduuro fun un. Awọn mẹta to ku ti wa lahaamọ ọgba-ẹwon to wa ni Oke Kura.

Ọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ni igbẹjọ wọn yoo tun maa tẹ siwaju.

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.