Awọn mẹrin ti wọn fẹsun kan pe wọn pa Sunday labule Oniṣọọṣi ti foju bale-ẹjọ

Spread the love

Lori ẹsun pe awọn afurasi mẹrin kan, Emmanuel Chidi Nweke, ẹni ọdun mejidinlogoji, Nworu Emmanuel, ẹni ogun ọdun, Sunday Ajaga, ẹni ọdun mejidinlogoji ati Anthony Oyin to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji lọwọ ninu iku ọkunrin ẹni ọdun metadinlọgbọn kan, Sunday Igere, ni wọn fi foju wọn bale-ẹjọ.
Awọn afurasi ti wọn n jẹjọ ipaniyan ọhun ni wọn fẹsun igbimọ-pọ lati gbẹmi eeyan kan wọn. Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe ṣalaye, ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, ni wọn huwa naa labule Oniṣọọṣi, nitosi Ẹpẹ, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo.
Wọn ni igi ni awọn eeyan yii la mọ Samuel lori, eyi to ṣokunfa iku rẹ.
Esun mejeeji ti wọn fi kan wọn ni Agbefọba Suleiman Adebayọ sọ pe o tako abala ofin ọọdunrun o le mẹrinlelogun ati ọọdunrun o le mẹrindinlogun ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo tọdun 2006.
Ninu ẹbẹ ti Adebayọ fi siwaju adajọ lo ti sọ pe ki wọn fi awọn afurasi ọhun pamọ sọgba ẹwọn, nitori ẹsun ti wọn fi kan wọn kọja eyi ti ile-ẹjọ majisreeti le gbọ labẹ ofin.
Awọn ojulowo ati ẹda iwe ẹsun ọhun lo ṣeleri pe oun yoo fi ṣọwọ si ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran lati le mu iṣẹ wọn ya.
Abilekọ Victoria Bob-Manuel gba ọrọ si aṣoju ileeṣẹ ọlọpaa naa lẹnu, o si paṣẹ pe ki wọn lọọ fi wọn pamọ si ọgba ẹwọn Olokuta, titi asiko ti awọn yoo fi ri imọran lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu to n bọ, lo sun igbẹjọ mi-in si.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.