Awọn meji ti wọn ba ọja ileeṣẹ ti wọn ti n ṣiṣẹ jẹ dero kootu l’Ekoo

Spread the love

Miliọnu kan Naira ati oniduuro meji niye kan naa ni Adajọ M.O Tanimọla ti kootu Majisreeti to wa ni Ikẹja, fi faaye beeli silẹ fun awọn afurasi ọdaran meji kan, Amadi Nkechi ati Yusuf Ibrahim.
Ẹsun ti wọn si wọ wọn lọ si kootu fun ni pe wọn ba ọja ileeṣẹ to n ṣe nnkan mimu ẹlẹridodo, Chi Limited jẹ. Ẹsun mẹta ọtọọtọ, iyẹn igbimọ-pọ huwa ọdaran, biba dukia eeyan jẹ ati hihuwa to le da omi alaafia ilu ru ni wọn fi kan wọn ni kootu.
Ọja naa ti wọn ni iye owo rẹ to miliọnu mẹjọ abọ Naira, ni wọn ni ki awọn mejeeji ti wọn n ṣiṣẹ awakọ nileeṣẹ yii lọọ ja si ilu Benin ati Onitsha, ṣugbọn awọn ọlọpaa sọ pe awọn afurasi yii tun ko awọn ẹru mi-in ti ki i ṣe ti ileeṣẹ, ẹru ti wọn si gbe naa lo ba awọn ọja naa jẹ. Awọn oṣiṣẹ ajọ Aṣọbode to yẹ ọkọ ọhun wo lo ṣakiyesi pe ki i ṣe ọja ileeṣẹ Chi ni wọn fi i ko, awọn ni wọn si ta ileeṣẹ naa lolobo.
Aohondoemba Koti to jẹ aṣoju ileeṣẹ ọlọpaa ni kootu sọ pe ọjọ kẹrinla, oṣu to kọja, ni awọn afurasi naa huwa yii, ẹsun naa si tako awọn ofin to de iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko n ṣamulo rẹ.
Ọjọ kejila, oṣu kọkanla, yii, lo sun igbẹjọ mi-in si.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.