Awọn kọmiṣanna tuntun gba idanilẹkọọ ọlọjọ mẹrin l’Ekoo

Spread the love

Adefunkẹ Adebiyi

Ọjọ mẹrin gbako ni idanilẹkọọ fi waye fawọn kọmiṣanna tuntun atawọn ọga agba (Permanent secretaries), ti wọn ṣẹṣẹ bura fun nipinlẹ Eko lọsẹ to kọja, lori bi wọn yoo ṣe ṣakoso daadaa nipinlẹ yii.

Ileetura Eko Hotel And Suite, Victoria Island, l’Ekoo, ni idanilẹkọọ ti akori ẹ n jẹ’Delivering the Lagos of our dreams’ ọhun ti waye, ti awọn agba ọjẹ lẹka iṣakoso aladaani ati tijọba si ti fun awọn alaṣẹ tuntun yii nidanilẹkọọ to ye kooro.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori idanilẹkọọ naa lọjọ Satide ti aṣekagba waye, kọmiṣanna tuntun feto iroyin ati ọgbọn inu, Gbenga Ọmọtọṣọ, ṣalaye pe kawọn ara Eko foju sọna fun Eko tuntun ti ohun ti wọn ti n fẹ lati ọdun pipẹ yoo ti waye. O ni ẹkọ tawọn gba yii ti fi ẹsẹ awọn le oju ọna tawọn yoo gba ṣiṣẹ, gbogbo ohun tawọn kọmiṣanna atawọn ọga agba ni minisiri nilo lawọn ti mọ, bawọn ba si ti n de ọfiisi lọjọ Aje, ọsẹ yii, iṣẹ ti yoo sọ Eko dọtun bẹrẹ niyẹn.

Diẹ ninu awọn ti wọn wa nibẹ lọjọ naa ni, olori oṣiṣẹ nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Muri Okunọla, Ajibọla Pọnnle; kọmiṣanna fọro owo ifẹyinti, Samuel Egube to wa fun iṣuna owo atawọn mi-in.

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.