Awọn kan ni ọrọ oṣelu lo wa nidii bọmbu to pa eeyan kan n’Ile-Ifẹ

Spread the love

Bo tilẹ jẹ pe ko ti i si ẹri lati fidi ẹ mulẹ, awọn araalu kan nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe afaimọ ko ma jẹ pe awọn oloṣelu ni wọn wa nidii bọmbu nla kan to dun, to si wo ile alaja kan palẹ tuu-tuu, ninu eyi ti eeyan kan ti padanu ẹmi rẹ laduugbo Mọọrẹ, niluu Ile-Ifẹ, nipinlẹ Ọsun, ni Satide, ọjọ Abamẹta, to lọ yii.

Ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ niṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ, yatọ si ile nla ti bọmbu naa da wo, bẹẹ lo tun jo ileeṣẹ kan ti wọn ti n ta oogun oyinbo atawọn dukia mi-in ti wọn ṣiro si ọpọlọpọ miliọnu naira. Ohun ti awọn eeyan kọkọ n sọ pe o ṣee ṣe ko fa ijamba naa ni ti ede aiyede laarin awọn mọlẹbi ẹni to ni ile ọhun to ku ninu oṣu kọkanla, ọdun to kọja, iyẹn 2017. Ni gẹrẹ to ku lawọn mọlẹbi ti dide ogun sira wọn lori bi wọn yoo ṣe pin ogun ile ọhun. Ọkan lara awọn araadugbo si sọ pe o ṣee ṣe ko ṣe pe ọkan ninu awọn mọlẹbi yii lo fẹẹ fi ọrọ yii ṣe kaka ki eku ma jẹ sese, a fi ṣe awadanu.

Ṣugbọn ṣaa o, awọn eeyan mi-in tun n foju ọrọ oṣelu to n ṣẹlẹ nipinlẹ Ọṣun ati niluu Ile-Ifẹ, nibi ti ọkan ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore, ti fi ẹgbẹ naa silẹ lati lọọ dije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu mi-in, ti wọn si fa kaadi ẹgbẹ wọn ya wo ọrọ ọhun.

Wọn ni, ‘Afaimọ ko ma ṣe pe ṣe ni awọn oloṣelu n mura ogun nitori wahala to ṣee ṣe ko waye lasiko idibo to n bọ, ti wọn si n ṣeto awọn nnkan ija ti wọn le fi koju awọn alatako wọn, ṣugbọn ti ọrọ bẹyin yọ, to fi jẹ ki bọmbu ọhun yin lojiji.

‘Ṣẹyin naa mọ pe ọrọ oṣelu ilẹ yii ti kuro leyii ti ẹni ti ko ba ni jagidi-jagan le ba wọn da si. Tọọgi atawọn ohun ija oloro lawọn oloṣelu n lo bayii lati fi du ipo, ko si si ohun ti wọn ko le ṣe lati foju awọn alatako wọn gbolẹ, eyi lo jẹ ka maa wo o pe ki awọn ọlọpaa ti wọn n ṣewadii iṣẹlẹ yii tun tanna wo ero ọkan awọn araalu yii.’

 

(78)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.