Awọn gomina ilẹ Yoruba fẹẹ ṣeto awọn agbofinro ti yoo maa ṣọ titi ijọba

Spread the love

Lori ọrọ aabo, awọn gomina ilẹ Yoruba fẹẹ ṣeto awọn agbofinro ti yoo maa ṣọ oju ọna wọn.

Gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun, lo sọrọ naa niluu Abẹokuta lanaa, nibi apero kan to ṣe lati fi ṣalaye erongba ijọba rẹ faraalu.

O ni ko si oniṣowo ti yoo fẹẹ da ileeṣẹ silẹ ladugbo to ba ri i pe ijọba ibẹ ko le ṣeto aabo to peye fẹmi oun ati ileeṣẹ toun da silẹ.

O tẹsiwaju pe awọn ẹṣọ alaabo naa yoo wa kaakiri awọn oju-ọna marosẹ apa Iwọ-Oorun Guusu orilẹ-ede yii lati wawọ awọn ọmọ jaduku ti wọn n fojoojumọ jiiyan gbe fi gbowo lawọn ipinlẹ wọn bọlẹ.

Bẹẹ naa no aarẹ ana, Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ṣepade pẹlu olori awọn Hausa/Fulani ilẹ Yoruba niluu Abẹokuta lori ọrọ eto aabo to mẹhẹ nilẹ yii.

Ọbasanjọ ni ọrọ awọn ajinigbe naa ki i ṣe nnkan ti ẹni kan le da yanju o, o ti kọja ohun ti wọn yoo maa ti ẹbi rẹ sira wọn lori, o ti di ohun ti gbogbo awọn gbọdọ jọ sowọpọ lati wa nnkan ṣe si i.

(14)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.