Awọn Fulani darandaran meji ko sọwọ ọlọpaa fẹsun idigunjale ti wọn fi kan wọn.

Spread the love

Ahaamọ ọgba ẹwọn to wa ni Mandalla nile-ẹjọ majisreeti ilu Ilọrin paṣẹ pe ki wọn ṣi fi awọn darandaran meji; Abubakar Mohammed ati Mohammed Isha, pamọ si lori ẹsun idigunjale.

Iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fi han pe awọn olujẹjọ yii lo maa n da awọn awakọ ati ero ọkọ lọna ni ọna Ilọrin si Ogbomọṣọ, ti wọn si maa n ja wọn lole.

Nigba ti ọwọ tẹ wọn, awọn ọlọpaa ba ọkada mẹta, foonu Nokia marun-un, foonu I-phone, ẹrọ ayaworan, ẹrọ kọmputa agbeletan ati awọn ẹgba ọrun lọwọ wọn.

Ọlọpaa to n ṣoju ijọba nile-ẹjọ, Abdullahi Sanni, sọ fun adajọ pe awọn araadugbo Ọlọrunṣogo to wa ni titi marosẹ Ilọrin si Ogbomọṣọ lo ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo tọwọ fi tẹ awọn afurasi naa.

Ẹsun meji ọtọọtọ to da lori igbimọ-pọ lati huwa ọdaran ati idigunjale ni wọn fi kan wọn ni kootu.

Nigba ti ile-ẹjọ ka ẹsun naa si wọn leti, wọn ni awọn ko jẹbi.

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.