Awọn Fulani darandaran lo ji wa gbe, o da mi loju daadaa – Chiemela Iroha

Spread the love

*A ti mu awọn afurasi mẹta lori rẹ-Ọlọpaa

Kayọde Ọmọtọṣọ, Abẹokuta

Ọkan ninu awọn ti wọn ji gbe lọna Ṣagamu si Benin lọsẹ to kọja ti wọn lo jẹ ọmọ gbajumọ alawada nni,  James Iroha, Chiemela Iroha ti ni ko si ani-ani pe awọn Fulani darandaran lo ji awọn gbe. Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Abẹokuta, ni olu ileeṣẹ ọlọpaa lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, Iroha ni o fẹẹ to kilomita ọgbọn ti awọn fẹsẹ rin ninu aginju. Ọkunrin yii ni ṣe ni awọn ajinigbe naa sọ fun awọn pe dandan ni ki awọn san owo ọta ibọn ti awọn yin mọ gbajumọ kan ti awọn fẹẹ ji gbe, ṣugbọn to sa lọ mọ awọn lọwọ.

Iroha ni ohun to fi awọn eeyan naa han gẹgẹ bii Fulani ni ede wọn ti wọn n sọ. Ọkunrin naa ni fun ọjọ mẹta ti awọn fi wa lọdọ wọn, awọn eeyan naa ko fun awọn lounjẹ, bẹẹ ni wọn ko fun awọn lomi mu rara.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “ohun to mu ki ẹru ba wọn ni igba ti wọn ri ọkọ ofurufu awọn ọlọpaa to n fo loke, idi niyẹn ti wọn si ṣe fi wa silẹ, ti wọn sa lọ. Mo fi asiko yii dupẹ lọwọ awọn ọlọpaa fun iṣẹ akinkanju ti wọn ṣe”

O tẹsiwaju pe awọn Fulani ajinigbe naa ni ohun ija oloro pupọ nikaawọ wọn, bẹẹ si ni wọn ṣe inu aginju ti wọn n gbe naa bii aafin ni. Nigba ti Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Bashir Makama, n sọrọ, o ni yatọ si iroyin to n lọ nigboro pe awọn maraarun ti wọn ji gbe naa jẹ pasitọ ijọ Ridiimu, o ni ẹni kan pere lo jẹ diakoni ijọ naa, obinrin si ni. Makama ni ọpọlọpọ nnkan ni awọn ọlọpaa tun ṣakiyesi laginju naa, ṣugbọn oun ko ni i fẹ ki awọn oniroyin gbọ nipa rẹ bayii.

Ọga ọlọpaa yii ni, “mi o mọ nipa ti owo idoola ti awọn eeyan n sọ pe awọn ti wọn ji gbe naa san rara.’’ Idahun to fun awọn to n beere boya awọn ti wọn ji gbe yii sanwo idoola ki wọn too gba wọn silẹ niyi. O fi kun un pe awọn ti mu afurasi mẹta lori iṣẹlẹ yii, nitori oun tẹle wọn debẹ.”

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.