Awọn Fulani ṣeku pa ọlọkada niluu Irawọ

Spread the love

Lọwọlọwọ bayii, inu ibanujẹ nla ni awọn mọlẹbi Balọdẹ, niluu Irawọ, nijọba ibilẹ Atisbo, nipinlẹ Ọyọ, wa, pẹlu bi awọn Fulani darandaran ṣe pa ọkan ninu awọn ọmọ wọn.
Wale Babalọla, lorukọ ọmọ ti wọn gbẹmi rẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja. Akọroyin wa ri i gbọ pe ọna to lọ siluu Alenibare lati ilu Irawọ, ni awọn Fulani ti wọn to bii mẹwaa niye ti da ọkunrin yii lọna, ti wọn si pa a.
Wale ti inagijẹ rẹ n jẹ Wale Big, ni wọn ṣẹburu rẹ lasiko to n gbe iyawo rẹ lọọ ra elubọ lọja Alenibare, eyi to fẹẹ to bii kilomita marundinlaaadọta siluu Irawọ.
Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun akọroyin wa pe lasiko ti ọmọkunrin naa n fi ọkada gbe iyawo re lọ ni awọn Fulani naa ṣadeede jade, ti wọn si tun da awọn mẹfa mi-in lọna, nibẹ ni wọn si ti gba owo, foonu ati awọn dukia wọn gbogbo. A ri i gbọ pe nibi ti Wale dojubolẹ si ni wọn ti lọọ fa a dide, ti wọn si mu un wọ igbo lọ, nibẹ ni wọn si ti yinbọn fun un lagbari, ni wọn ba sa lọ.
Alaga ẹgbẹ idagbasoke ọmọ ilu Irawo ile, Ọgbẹni Ibraheem Ajayi, sọ fun akọroyin wa pe ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ fijilante lo pe oun sori foonu, lẹsẹkẹsẹ loun si ṣeto ikọ awọn fijilante pe ki wọn ṣawari awọn to ṣiṣẹ ibi naa. O ni lẹyin wakati meji ni wọn ri oku oloogbe yii pẹlu ọta ibọn lagbari rẹ.
Teṣan ọlọpaa Tede ni wọn kọkọ gbe oku Wale lọ, ko too di pe wọn gbe e lọ si ileewosan aladaani kan to wa niluu Agọ-Arẹ.
Nigba ti Baba oloogbe naa, Gedion Babalọla, ẹni aadọrin ọdun, n ba akọroyin wa sọrọ, o rawọ ẹbẹ sijọba lati ṣaanu ẹbi naa, o ni oloogbe yii lo n tọju oun ko too di pe iṣẹlẹ ajalu naa ṣẹlẹ.
Ajoriiwin ilu Irawọ, Ọba Musiliudeen Ademọla Ọlalere, rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati ṣafikun awọn ikọ alaabo lagbegbe naa, nitori o ti n di gbogbo igba ti awọn Fulani darandaran maa n ṣeku pa awọn eeyan agbegbe yii.
Aago meji oru ni wọn sinku oloogbe naa sinu agboole wọn niluu Irawọ, o fi iyawo meji atawọn ọmọ meji saye lọ.

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.