Awọn eleyii ki i ṣe eeyan, ẹlẹtan lasan ni wọn

Spread the love

Bo ṣe jẹ pe bi iku ile ko ba pa ni, tode ko le paayan, bẹẹ naa lo jẹ bi aṣaaju kan ba wa, bi awọn ti wọn yi i ka ko ba ti i ṣubu tabi ki wọn ko aburu ba a, ko si araata to le ti i ṣubu tabi ko aburu kan ba a. Aarẹ Muhammadu Buhari n ro pe awọn Saraki, awọn Ọbasanjọ, awọn Babangida ati Danjuma lọta oun, bẹẹ ki i ṣe bẹẹ, awọn ti wọn yi i ka gan-an ni ọta rẹ. Awọn yii ni wọn ki i ba a sọ ootọ ọrọ, wọn ko si niṣẹ meji ti wọn n ṣe ju ki wọn maa tan an lọ. Ọkan ninu awọn olori ẹlẹtan yii ni Rotimi Amaechi, minisita fun eto irinna ọkọ gbogbo. Ọkan ninu awọn ọmọ PDP to bọ sinu APC ni, ọkan ninu awọn ti wọn si nawo rẹpẹtẹ lati ri i pe Buhari wọle ni 2015 ni. Ṣugbọn ọkunrin yii wa ninu awọn ti wọn ko le ba Buhari sọ ododo ọrọ, wọn yoo maa tan an ni. Lọsẹ to kọja yii, o ni pẹlu gbogbo ohun to n lọ lorilẹ-ede yii, koda ki ara Buhari ma ya, ko wa lori idubulẹ aisan lọsibitu, bi wọn ba dibo ni Bauchi, Sokoto ati awọn ipinlẹ mi-in, oun ni yoo wọle, lai dide, lai ba wọn sọrọ kan. Lara awọn ti wọn n pe ọmọ Naijiria ni oponu ati alailọgbọn leleyii. Oun naa mọ lọkan ara rẹ o, o mọ pe awọn nnkan kan wa to ku diẹ kaato ninu ijọba yii o, o mọ pe awọn kinni kan wa ti Buhari gbọdọ ṣe ti inu awọn araalu yoo fi pada yọ si i o, ṣugbọn ko jẹ sọ bẹẹ fun Buhari, bi yoo ti ṣe maa tan an niyẹn, ki iyẹn le sọ pe ẹyin oun lo wa, ki wọn ma si ṣe gba ipo minisita to wa kuro lọwọ rẹ. Awọn yii ni ki i jẹ ki ilu lọ siwaju, nigba to jẹ tara wọn nikan ni wọn n ṣe, wọn ko ṣe ti ijọba tabi ti olori ijọba, bẹẹ ni wọn ko si ṣe ti araalu rara. Awọn yii ni wọn yoo ti Buhari ṣubu bi ko ba mura, awọn yii ni yoo ba ijọba rẹ jẹ, afi to ba tete ṣilẹkun fun wọn, ko le wọn kuro ninu ijọba rẹ, ko si le wọn kuro lẹgbẹẹ rẹ, ko wa awọn olododo ti yoo le ba a sọ ootọ ọrọ nigbakigba, ati nibikibi, nitori iyẹn nikan lo le ran an lọwọ.

(55)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.