Awọn ẹgbẹ oṣelu to jade ni 1978 le lọgọrun-un, ni wọn ba gbe iṣẹ aye le FEDECO lọwọ

Spread the love

Ojoojumọ lawọn ẹgbẹ oṣelu n pọ si i. Ni 1978 la n wi o, lasiko ti ijọba awọn ologun, labẹ Ọgagun Agba Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ n gbero lati gbe ijọba pada fun awọn oloṣelu ti wọn ti n ṣejọba tẹlẹ nigba ti Naijiria ṣẹṣẹ gbominira, ko too di pe awọn ologun gbajọba naa lọwọ wọn. Ni 1978 ti awọn Ọbasanjọ bẹrẹ eto yii, o ti di ọdun mejila geere ti awọn ologun ti n ṣejọba naa lọ. 1966, ni ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kin-in-ni, ọdun naa, lawọn ṣọja kan fibọn gbajọba ni tiwọn, Kaduna Nzeogwu lorukọ ọkunrin to ṣaaju wọn, wọn si yinbọn pa ọpọ awọn oloṣelu igba naa ki wọn too gbajọba lọwọ wọn. Ṣugbọn Kaduna Nzeogwu yii ko le ṣe ijọba rara nitori Mejọ (Major) loun ninu ologun, ẹni to si jẹ ọga awọn ṣọja pata nigba naa, Aguiyi Ironsi, ni wọn pada gbejọba fun.

Ironsi paapaa ko le ṣejọba naa debi kan rara, oṣu mẹfa pere lo lo ti awọn ṣọja ilẹ Hausa fi gbajọba lọwọ oun naa, nitori wọn sọ pe ijọba awọn ọmọ Ibo ni, ati nitori pe ki awọn ti wọn jẹ Ibo le sọ ara wọn di olori Naijiria ni tipatipa ni wọn ṣe pa awọn oloṣelu ati ṣọja to jẹ aṣaaju lati ọdọ awọn nilẹ Hausa. N ni wọn ba tun yibọn pa Ironsi, awọn bii Muritala Muhammed, Yakubu Danjuma, Ibrahim Babangida, Shehu Musa Yaradua, Muhammadu Buhari, Jeremiah Useni, Sani Abacha, pẹlu awọn ṣọja ilẹ Hausa bẹẹ ni wọn ditẹ naa. Ọjọ buruku lọjọ ọhun, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 1966, lọjọ ti wọn yinbọn pa Ironsi nile Ijọba n’Ibadan, nigba to waa ki Adekunle Fajuyi ti i ṣe gomina ologun. Awọn mejeeji ni wọn jọ pa.

Ẹyin naa ni wọn fi Yakubu Gowon ṣe olori tiwọn, ti awọn ọmọ Ibo ti wọn jẹ ṣọja naa si lawọn ko gba, ti Emeka Ojukwu si ṣaaju awọn, ti ọrọ si di ogun abẹle. Ogun abẹle naa le, nitori nigba naa la gbọ orukọ awọn bii Adeyinka Adebayọ, Alani Akinrinade, Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Alabi Isama, ati awọn bẹẹ bẹẹ lọ. Bi wọn ti jagun abẹle tan ni Yakubu Gowon ti n leri pe oun yoo gbejọba silẹ fawọn alagbada, o ni awọn oloṣelu yii yoo bẹrẹ si i ṣejọba lati ọdun 1976 lọ. Ṣugbọn ẹnu lasan lo fi n sọrọ naa, nigba ti yoo si fi di ọdun 1975, ijọba to n ṣe naa ti dun mọ ọn debii pe ko fẹẹ gbe kinni naa silẹ, o ni Naijiria ko ti i ṣetan ijọba alagbada. Iyẹn lo bi awọn Muritala ninu, ni wọn ba fibọn gbajọba lọwọ oun naa, wọn ni ko wa ibi kan lọọ jokoo si na. Muritala lo ṣeto, to ni ijọba toun yoo gbe kinni naa silẹ fawọn alagbada lọdun 1979, ti gbogbo ọmọ Naijiria si patẹwọ fun un.

Amọ bo ti la eto naa kalẹ ni awọn ṣọja mi-in binu ẹ, ti wọn si ditẹ mọ oun naa lọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 1976, ti wọn pa a nipakupa. Ṣugbọn ijọba naa ko bọ si ọwọ awọn Dimka ti wọn yinbọn pa a, ọwọ Oluṣẹgun Ọbasanjọ to jẹ igbakeji Muritala nijọba bọ si, oun ati awọn ti wọn ti n ba Muritala ṣiṣẹ tẹlẹ si mu iṣẹ ijọba naa ni pataki, wọn ni gbogbo ohun ti Muritala dawọle lawọn yoo yanju pata. Bi awọn Ọbasanjọ si ti wi yii naa ni wọn  n ṣe, awọn ni wọn ṣeto pe wọn yoo gbejọba silẹ fawọn oloṣelu, ti wọn si bẹrẹ eto naa pẹrẹwu ni 1978, ti wọn ni ki awọn oloṣelu bẹrẹ si i da ẹgbẹ tiwọn silẹ, ti wọn gbe ofin kuro lori ofin to de oṣelu ṣiṣe, ti ọpọ awọn oloṣelu si rọ jade. Ṣugbọn laarin oṣu kẹsan-an si ikẹwaa ọdun naa, lẹyin ti awọn ologun ti gbẹsẹ kuro lori ofin oṣelu yii, awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn ti tu jade ti le ni ogoji, kaluku si n sọ pe awọn lawọn yoo gbajọba.

Awọn ẹgbẹ kan ti jade ti wọn ni awọn ni ẹgbẹ agbẹ, Farmers’ Welfare, wọn ni irọrun awọn agbẹ nikan lawọn yoo wa ni tawọn, ki gbogbo agbẹ maa bọ lọdọ awọn, bi wọn ba le fi ibo tiwọn gbe ẹgbẹ awọn wọle, ọrọ ti buṣe ree. Awọn kan ni ẹgbẹ tawọn, itọju awọn obinrin lo wa fun, nitori ọjọ pẹ ti iya ti n jẹ awọn obinrin, bi awọn ba si le wọle, obinrin lawọn yoo gbe ade ijọba awọn le lori, ti wọn yoo fi le mọ pe awọn ka wọn si lawujọ, nitori awọn obinrin ni iya gbogbo wa. Awọn kan lawọn oniṣẹ-ọwọ lawọn tori ẹ jade, tori awọn niya n jẹ ju, awọn lawọn si fẹẹ ṣeto biya o ṣe ni i jẹ wọn mọ, ki wọn le maa jere iṣẹ ti wọn n ṣe. Awọn kan ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ni tawọn, awọn ko mọ ẹlomiiran ti iya n jẹ ju awọn oṣiṣẹ ijọba lọ, nitori gbogbo bi wọn ti n ṣiṣẹ to, wọn ko ri anfaani gidi jẹ nidii iṣẹ, kaka bẹẹ, niṣe lawọn ti wọn n ṣejọba n fiya jẹ wọn. Wọn ni nitori ẹ lawọn ṣe fẹẹ gbajọba fun wọn.

Bi ẹgbẹ kan ṣe n ti ọtun jade ni awọn mi-in n ti osi jade, ẹgbẹ oniru, ẹgbẹ alata, gbogbo rẹ si n pọ si i lojoojumọ ni. Ọrọ naa da ijọba ologun loju ru, wọn ko si tete mọ ibi ti wọn yoo gbe kinni naa gba, bawọn ẹgbẹ oṣelu ṣe pọ to bayii jọ awọn naa loju gan-an. Wọn n sọ fawọn to sun mọ wọn pe awọn ko ma mọ pe bi kinni naa yoo ṣe pọ to ree, ẹgbẹ oṣelu meloo ni wọn waa fẹẹ ko fawọn ọmọ Naijiria, awọn meloo ni yoo wọle, awọn wo ni ko si nibi kankan i lọ. Bawo ni wọn ko ṣe ni i jẹ ki ẹgbẹ rẹpẹtẹ doju eto yii ru, paapaa fun awọn ọmọ Naijiria ti wọn ki i ṣe oloṣelu, to jẹ jẹẹjẹ tiwọn lawọn n lọ. Loootọ si ni, ọrọ naa ti di nnkan nigboro, ti awọn oloṣelu ti ko gbogbo araalu ni ipapamọra, to jẹ ko si ọrọ mi-in to n lọ niluu mọ ju ọrọ oṣelu lọ. Nigba naa ni kaluku bẹrẹ si i sọrọ, pe ki wọn tete wa bi wọn yoo ṣe ṣe ọrọ awọn ẹgbẹ oṣelu to rọ jade yii si, ko ma di pe wọn oo ba nnkan jẹ o.

Kin ni wọn waa fẹẹ ṣe siru ọrọ bẹẹ, nigba ti ijọba ologun ti sọ pe awọn ko fẹẹ da si kinni kan, awọn ọmọ Naijiria ni ki wọn yan ẹni ti wọn ba fẹ funra wọn. Ọkunrin ọmọ ẹgbẹ oṣelu NPP kan lo kọkọ mu amọran wa, ọga kan ninu ẹgbẹ naa lati ipinlẹ Plateau  ni. E. A. Isandu lorukọ toun. Lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa, ni 1978, loun jade, o ni ọrọ to wa nilẹ yii ko le rara, o ni bi ijọba apapọ ba fẹẹ fi opin sọrọ awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn n ṣu jade bi esu yii, ohun ti wọn yoo ṣe wa, koda oogun ti oun fẹẹ kọ wọn yii ko na wọn lowo rara. O ni oun ti ki ijọba tete sare ṣe ni ki wọn tẹ iwe akaunti ijọba wọn jade, ati ti ipinlẹ kọọkan. O ni iwe akaunti ti wọn yoo tẹ jade yii, yoo sọ iye ti ijọba ipinlẹ kọọkan ni lọwọ, ati iye ti wọn n gba loṣooṣu, ati iye bukaata to wa lọrun wọn ati gbese ti wọn jẹ, ati awọn inawo airoti ti wọn yoo tun maa na.

Wọn ni ki lo de to fi sọ bẹẹ, ati pe ki lo kan akaunti ninu ọrọ awọn ẹgbẹ oṣelu to n jade. Iru oogun wo ree! Isandu ni toun kuku ye oun, o lo ye oun daadaa paapaa. O ni bi ijọba ba ṣe awọn akaunti yii jade, ti wọn tẹ iye owo ti awọn ipinlẹ n gba sita ati iye gbese ti wọn jẹ, o ni ọpọlọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu yii ati awọn ti wọn n gbe wọn jade ni wọn yoo parẹ. O ni ohun to n ṣe wọn ni pe owo wa lapo ijọba, owo wa nile ijọba, awọn yoo si ri ọpọlọpọ owo nibẹ, ṣugbọn ti wọn ba ti ri i pe ko si owo nibẹ, gbese lo wa nibẹ, ati pe ẹni to ba gbajọba ko le ri owo kan ji, awọn ti wọn ba fẹẹ wa si idi oṣelu yoo ronu wọn wo lẹẹmeji, awọn to ba si jẹ owo lawọn n wa bọ yoo tete mọ pe ko sowo nibẹ fun wọn, wọn yoo si jokoo wọn jẹẹ, tabi ki wọn tete wa nnkan mi-in maa ṣe. O ni ki awọn ti wọn ko ba mọ tete yaa mọ o, ọpọ awọn ti wọn n ko ẹgbẹ jade yii, owo ni wọn n wa.

Ọrọ ti Isandu n sọ yii, ṣe ẹni to ba mọ oju Ogun ni i pa obi n’Ire ni, ohun ti ọkunrin naa mọ lo n sọ. Akọwe agba ileeṣẹ ijọba loun naa tẹlẹ, o si ṣẹṣẹ fẹyinti ko too bọ sagbo awọn oloṣelu ni. O ni bi ọpọlọpọ awọn eeyan ba mọ pe owo ti ijọba apapọ yẹ ko fun awọn ipinlẹ fun oṣu to kọja, wọn ko ti i ri i san, bẹẹ oṣu mi-in lo ti fẹẹ pari yii, o ni kia ni wọn yoo jokoo wọn jẹẹ, ti wọn yoo mọ pe ko si owo kan nibi kan ti ẹnikan le ko jẹ, apo ijọba gbẹ. N lawọn eeyan ba n pariwo, wọn ni kin ni ọkunrin yii n sọ yii, alaye ẹ yii ma ri bakan o. Ṣugbọn awọn mi-in ti wọn mọ pato ọrọ ni ootọ lo sọ, wọn ni ọpọ awọn ti wọn n ko agbada kiri wọnyi, wọn n ko kinni naa kiri nitori owo ni, ki i ṣe nitori ohun meji. Wọn ni awọn ti wọn tori araalu wa sidii oṣelu ko to nnkan, awọn ti wọn n wa owo lo pọ ninu wọn, asiko si ti to ti awọn ko mẹsẹ gbọdọ yọ.

Bẹẹ, bi eeyan ba fẹẹ sọ ọ, ọrọ naa ti da wahala silẹ ri o. Ọrọ ti Isandu sọ yii ni. O ti da wahala silẹ nigba kan. Nitori Aminu Kano lo kọkọ sọ bẹẹ, o ni ki ijọba tẹ iye owo ti wọn n na, iye ti wọn n ri, ati iye gbese ti wọn jẹ. O ni pataki ti kinni naa yoo ṣe fawọn oloṣelu ni pe wọn yoo mọ iye to wa ninu apo ijọba, wọn yoo si le mọ eto ati ileri ti awọn yoo ṣe fawọn eeyan, ko ma di pe awọn lọọ sọrọ kan, tabi ki awọn ni awọn yoo ṣe kinni kan, ko waa di pe apa owo ko ni i ka a mọ. Nigba to sọrọ yii, ọrọ naa ko ba awọn ologun ti wọn n ṣejọba ninu mu rara. Ọgagun James Olulẹyẹ to jẹ oun ni minisita fun eto inawo ni iru ọrọ wo niyẹn, pe ọrọ ti Aminu Kano sọ, niṣe lo sọ ọ bii pe awọn ologun to n ṣejọba n fi kinni kan pamọ. O ni iwe to n beere yii, o wa ni Central Bank, nitori oṣooṣu ni wọn n tẹ ẹ jade, bo ba si rin gbẹrẹ wọ banki ọhun, wọn yoo fun un.

Ni gbogbo igba ti wọn n fa ọrọ yii ṣaa o, ajọ to fẹẹ ṣeto idibo naa, FEDECO, ti fi ọjọ ipade nla kan si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 1978 yii, wọn ni awọn ti mọ bi nnkan ṣe n lọ si, awọn si mọ bi awọn yoo ṣe fi ofin ati eto de ẹgbẹ oṣelu ti ko ba kun oju oṣuwọn, pe ti awọn ba ti gbe eto awọn jade, nigba ti yoo ba to bii ọjọ meloo kan, awọn ẹgbẹ oṣelu to n pariwo kiri yii yoo bẹrẹ si i jabọ nikọọkan, tabi ki wọn so mọ awọn ẹgbẹ mi-in, ti wọn ba mọ pe awọn fẹẹ maa ṣe oṣelu loootọ ni Naijiria. Alade Ọdunewu, alaaji ni, oun lọgaa awọn FEDECO ni ipinlẹ Eko, oun naa lo si kede ọrọ yii. O ni ki awọn eeyan ma wulẹ daamu ara wọn lori ọrọ awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn n jade yii, pe aala ni yoo fi oko ọlẹ han, nigba to ba ya, iyẹn laipẹ lai jinna, awọn araalu yoo mọ awọn ẹgbẹ oṣelu tootọ, wọn yoo si mọ awọn to jẹ wọn kan n dibọn lasan ni, wọn o to bẹẹ.

Ọrọ naa da bii pe o dun mọ ijọba ologun ninu, pe bi awọn to n ṣeto idibo ba ti gbe odinwọn jade, kaluku awọn ti wọn n pariwo kiri yii yoo wa ibi kan fidi le. O kan jẹ kinni naa ko dun mọ awọn oloṣelu ninu ni, wọn ni FEDECO fẹẹ fiyọ jabẹ, wọn fẹẹ bẹrẹ aṣeju, bẹẹ aṣeju ni baba aṣetẹ. Wọn ni ki lo kan wọn ninu ọrọ to wa nilẹ yii, pe ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria ibaa pe ẹgbẹrun mẹta, koda ki wọn jẹ ẹgbẹrun marun-un, eyi to ba wu awọn araalu ni wọn yoo dibo fun, ẹgbẹ ti wọn ko ba si dibo fun yoo ti mọ pe oun ko kun oju oṣuwọn niyẹn. Ewo waa ni ko jẹ FEDECO ni yoo maa halẹ mọ awọn, ti wọn yoo maa ni awọn yoo yọ orukọ awọn danu, tabi pe awọn ko ni i fi orukọ awọn silẹ, ohun to ba kan kaluku ni ko mojuto o, eyi ti wọn n sọ yii ko kan wọn, elubọ ni wọn waa ra lọja, ọmọ ẹran ṣe degba wọn. Koda awọn ẹgbẹ oṣelu nla paapaa sọrọ, wọn ni ki FEDECO so ewe agbejẹ mọwọ.

N lọga awọn FEDECO funra rẹ, Michael Ani, ba jade. O ni ki gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu yii fọkan ara wọn balẹ, ki wọn ma lo agbara wọn lori ọrọ ti ko to nnkan. O ni ọrọ to wa nilẹ yii ko le rara, akerengbe ni yoo juwe ibi ti wọn yoo ti ti okun bọ oun lọrun, awọn ẹgbẹ oṣelu funra wọn ni wọn yoo sọ eyi to kun oju oṣuwọn ninu awọn, ati eyi ti ko tilẹ yẹ ko jade ko pe ara rẹ ni ẹgbẹ oṣelu rara. O ni ko si ohun to le ninu ọrọ yii, nitori awọn ti wọn ba ti n ba eto ijọba Naijiria bọ, ati awọn agba laarin ilu gbọdọ mọ pe iru ohun to n ṣẹlẹ yii gbọdọ ṣẹlẹ ṣaa ni. O ni lati ọdun mejila sẹyin lawọn ijọba ti fofin de awọn oloṣelu, ti wọn o jẹ ki wọn sọrọ, ti wọn ko jẹ ki wọn rin irin ẹsẹ wọn tabi ṣe oṣelu to wu wọn, bẹẹ iṣẹ ti awọn mọ daadaa julọ niyẹn. Nigba ti wọn waa ṣi wọn silẹ lojiji yii, wọn yoo fọnka sigboro taara ni. Ohun to n ṣẹlẹ niyẹn.

Michael Ani ni ṣugbọn ohun to daju ni pe ko si oloṣelu kan ti yoo pe ara rẹ ni ẹgbẹ oṣelu bi ko ba jẹ pe FEDECO fọwọ si ohun ti wọn n ṣe, ti wọn si fun wọn ni sabukeeti, o ni wọn o baa ko ara wọn jọ ju bẹẹ lọ. O ni iroyin ti awọn n gbọ bayii ni pe awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn ti wa nigboro bayii ti le ni ọgọrun-un kan, ṣugbọn wọn ki i ṣe ẹgbẹ oṣelu nitori ko si eyi to ti i waa ba FEDECO lati gba iwe fọọmu pe ẹgbẹ oṣelu lawọn, ati pe awọn ti wọn tilẹ ti gba fọọmu naa ko ti i da a pada, bẹẹ o digba ti wọn ba da fọọmu wọn pada, ti awọn ba yẹ iwe ti wọn kọ wa wo ki awọn too mọ pe wọn le ṣe ẹgbẹ oṣelu loootọ, ti awọn yoo si fun wọn ni iwe aṣẹ. O ni ẹgbẹ mẹrin pere lo ti gba fọọmu, ko si si eyọ kan ninu wọn to ti i da fọọmu naa pada, bi wọn ba da a pada tan lawọn yoo too mọ pe wọn fẹẹ ṣe oṣelu loootọ, nitori awọn lawọn yoo fun wọn ni sabukeeti, ati iwe aṣẹ to ba yẹ gbogbo.

O jọ pe ohun ti Tunji Braithwaite gbọ ree to ta a lara kiji. Ṣe lọọya loun, oun si mọ ofin daadaa. Bii ọjọ kẹta ti Michael Ani sọrọ tirẹ yii, bi ẹgbẹ oṣelu Braithwaite ti wọn pe ni NAP (National Advance Party) ṣe di igba di agbọn tiwọn ree o, ni wọn ba kọri si olu ileeṣẹ awọn FEDECO yii l’Ekoo, iyẹn jẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹwaa, ni 1978, wọn ni awọn ti de o, awọn waa ba wọn lalejo bii ogun de. Awọn ọmọ ẹgbẹ NAP ti wọn wa nibẹ lọjọ naa jẹ mẹrin: Alaaji Waziri Kutigi, Umaru Dambo ati Franklin Moore ati Ajose Harrison, akọwe ẹgbẹ naa to ṣaaju wọn lọ. N lawọn ara FEDECO ba ni ṣe ko si nnkan, wọn ni awọn ti ṣeto gbogbo pari ni, awọn ti ṣe fọọmu ti wọn fawọn, awọn si ti ko gbogbo ẹri ti wọn n fẹ wa, awọn fẹẹ forukọ ẹgbẹ awọn silẹ, awọn ti pari gbogbo eto, ko si ohun to tun ku mọ, ki FEDECO fawọn niwee aṣẹ awọn.

 

 

Igbakeji akọwe FEDECO ni wọn sare ranṣẹ si, wọn ni ko waa gba ẹru tawọn eeyan NAP ko wa o. Oun naa si jade si wọn, o gba iwe naa lọwọ wọn, o ni ko si wahala mọ, bi awọn ba ti yẹwe ọhun wo, to jẹ gbogbo ẹ lo pe perepere bi wọn ti wi, wọn yoo gba sabukeeti wọn laipẹ jọjọ. Bayii lo jẹ NAP, ẹgbẹ Tunji Braithwaite, lo kọkọ ko iwe rẹ kalẹ ninu gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu ọdun 1978, o ta gbogbo wọn yọ. Ọrọ naa jo awọn UPN lara, wọn ko mọ pe ọkunrin naa yoo ba ibẹ yẹn yọ si wọn rara. Abi iru arifin wo ree! Lọjọ keji, iyẹn ni Ọjọbọ, ọjọ Alamisi, lawọn naa ba di ẹru wọn, wọn kọri si FEDECO, wọn ni awọn ti pari iwe tawọn tipẹ, awọn ko kan ti i raaye lati gbe e wa ni, ṣugbọn nigba awọn ọmọ ẹgbẹ NAP yii ti pe awọn nija, ẹru ree, kawọn akọwe maa yẹ ẹ wo lo ku, wọn yoo si ri i pe ko si kinni kan to yingin.

Lẹyin eyi, awọn ẹgbẹ oṣelu to ku ko le tete jade, o si ṣe diẹ kẹnikẹni too gburoo wọn.

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.