Awọn ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ọyọ pin ipo igbakeji gomina si Oke-Ogun

Spread the love

Agbegbe Oke-Ogun ni pupọ ninu awọn ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ọyọ pin ipo igbakeji gomina si. Bo tilẹ jẹ pe afojusun agbegbe naa ni pe ki wọn jẹ gomina ipinlẹ naa, ṣugbọn pẹlu eyi, o tumọ si pe wọn yoo tun ni suuru di ẹyi ọdun mẹrin mi-in.

ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe gbogbo awọn ọmọ agbegbe naa ti wọn ti ni i lọkan lati dije ni wọn ko ri tikẹẹti ẹgbẹ wọn gba. Lara wọn ni Amofin Adebayọ Shittu, ti ẹgbẹ APC, ẹni ti wọn sọ pe ko niwee-ẹri agunbanirọ,  Ẹnjinnia Rẹmi Ọlaniyan, ti ẹgbẹ oṣelu ADC, Moses Ọmọdewu, to wa lati agbegbe Itẹsiwaju naa padanu ipo ọhun sọwọAdebayọ Adelabu ti APC.

Ilu Ibadan lo ni ibo to pọ ju, nitori ijọba ibilẹ mọkanla ni wọn ni, lẹyin naa ni Oke-Ogun, ti wọn ni ijọba ibilẹ mẹwaa.

Idi eyi ni oludije fun ipo gomina lẹgbẹ APC, Adebayọ Adelabu, ṣe yan Samuel Modepoọla Egunjọbi to wa lati ijọba ibilẹ Iwajọwa gẹgẹ bii igbakeji rẹ, ti ẹgbẹ oṣelu ADC naa si yan Ọgbẹni Saheed Adejare Alaran, to wa lati ilu Iṣẹyin gẹgẹ bi igbakeji gomina fun Sẹnetọ Lanlẹhin.

Ni ti ẹgbẹ oṣelu PDP, ọrọ ipo igbakeji gomina ko ti i niyanju, ṣugbọn, o ṣee ṣe ki wọn mu Alaaji Ṣarafadeen Omirinde tabi Alhaji Taofeek Ọlanrewaju Olubori ti wọn jẹ ọmọ ilu Ṣaki.

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.