Awon eeyan sedaro awọn agunbanirọ mẹsan-an ti omi gbe lọ ni Taraba

Spread the love

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn eeyan ṣi n ṣedaro awọn agunbanirọ mẹsan-an ti omi gbe lọ nipinlẹ Taraba lọsẹ to kọja.

Koda, inu ibanujẹ nla obi awọn ọdọ ti wọn lọọ sinjọba nipinlẹ Taraba yii ṣi wa. Omi lo gbe mẹsan-an ninu wọn lọ lasiko ti wọn lọọ luwẹẹ ninu odo, koda, wọn ko ti i ri oku awọn meji mi-in ninu wọn titi di asiko ti a fi n kọ iroyin yii. Odo Mayo-Selbe to wa ni ijọba ibilẹ Gashaka, nipinlẹ naa, ni wọn ti lọọ gbafẹ, lasiko ti wọn si n ṣe eyi ni wọn pinnu lati luwẹẹ, leyii to mu ki omi gbe wọn lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Taraba, ASP David Missal, fidi ọrọ naa mulẹ fawọn oniroyin pẹlu alaye pe awọn mẹsan-an ninu awọn agunbanirọ mejilelogun ti wọn lọọ luwẹẹ ninu odo naa ni wọn padanu ẹmi wọn, awọn ọlọpaa si ti ri oku awọn meje yọ ninu wọn.

Missal ṣalaye pe iwadii awọn ọlọpaa fi han pe iji lile kan lo deede ṣẹ yọ lasiko ti awọn agunbanirọ naa n luwẹẹ lọwọ, eyi to fa a ti omi fi wọ mẹsan-an ninu wọn lọ, ti awọn yooku si ja raburabu lati doola ẹmi wọn.

Florence Yaakugh ti i ṣe adari ajọ agunbanirọ nipinlẹ naa fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ajalu nla gbaa lo jẹ fun ajọ naa. O fi kun un pe awọn ti n ṣa gbogbo ipa lati mọ orukọ wọn, awọn yoo si gbe e jade laipẹ.

(25)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.